Aare Buhari file America sile lo si London - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Saturday, 23 September 2017

Aare Buhari file America sile lo si London

Aare Muhammadu Buhari kuro nile America leyin to ti kopa ninu ipade ajo isokan agbaye eleekejilelaadorin iru e nilu New York lorile ede America.
Aare gbera ni nkan bii aago meje koja iseju marun un lale ojo Bo kuro nile itura re lo si ibudoko ofurufu JFK ki o to maa lo si London.
A ko tii mo ohun to n lo se ni London ati odiwon igba ti yoo lo nibe ki o to pada wa sile.
Laipe yii ni aare Buhari pada wa sile ni Naijria leyin to ti lo o le ni osu meta nilu London fun itoju ara re.
Lojo Isegun ni aare ka akosile Naijiria nile America ko to tun se ipade pelu Donald Trump aare ile America, Oba ile Jordan, Abdullah II, Aare ile Ghana, Nana Kuffour Addo ati akowe agba ajo isokan agbaye, Antonio Guterres.
Olubadamoran fun aare lori eto iroyin ati ipolongo, Ogbnei Femi Adesina ni:”Bi Aare Buhari se lo si New York ti n bi eso rere fun Naijiria paapaa lori bi Jordan se fun Naijiria ni oko ogun igba fun lilo”

O ni Buhari jiroro pelu awon olori lorisiirisii lori ona ajosepo fun idagbasoke.

No comments:

Post a Comment