Afoju Agbejoro Obinrin Omo Orile-ede Ethiopia Gbami Eye Agbaye - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Saturday, 30 September 2017

Afoju Agbejoro Obinrin Omo Orile-ede Ethiopia Gbami Eye Agbaye

 

Agbejoro afoju omo orile-ede Ethiopia ni o darapo gba ami eye ajafeto omo-eniyan ti odun 2017, eyi ti o tun je (Sweden  Alternative Nobel Prize).
Omo odun metadinlogoji ajafeto omo-eniyan Yetnebersh Nigussie ni won da lola million owo Sweden ($374.000) eyi ti apapo awon alami eye meteeta naa yoo pin.
Ami eye idalola naa waye latari akitiyan re, ni iyanju ipolongo lori eto awon akanda eda.
Arabinrin Yetnebersh Nigussie  so pe, “Mo bere ipolongo yii lai so fun enikankan, amo mo n fihan awon eniyan wi pe, mo le kopa tabi se ojuse lawujo, mo mo pe, mo je akanda eniyan amo mo kuju-osuwon, mo si to gbangba sun loye”.
“Mo fe ri agbaye kan, nibi ti ko si boya enikan n korira enikeji latari ailera tabi nnkan miiran”.
Yetnebersh Nigussie  fo loju nigba ti o wa ni omo odun marun-un, ni eyi ti won rip e, ko ja-mo nnkankan lawujo, amo, obi re fi si ile-iwe alakobere awon obinrin, ti o si n gbe ile-iwe naa ti o wa ni ilu Addis Ababa ti se olu ilu orile-ede Ethiopia, nibi ti igbe aye re ti yi pada.
O je okan lara awon obinrin meta ti won keko gboye agbejoro nile-eko giga fafiti ti o wa ni ilu Addis Ababa ni odun 2002, ninu eyi ti o fi ero igboran kawe fun odun marun-un gbako.
O se lalaye pe, “ inu oun dun lati kawe, tori pe, iwe kika je ona gboogi ti o le yii igbe aye akanda oun pada sir ere”.
Yetnebersh Nigussie je eni akoko lara awon afoju obinrin meta ti won lo sile-eko agbejoro, ni eyi ti o se idasile gbongan idanileko fun awon akanda eniyan nile-eko giga fafiti naa eyi ti mo si Ethiopia Center for Disabilities and Develoment (ECDD).
O ti gba olokan-o-jokan ami eye, amo se lalaye pe, ami eye yii ni o tobi ju ninu gbogbo ami eye ti oun ti gba, Nigussie ni oko pelu awon omobinrin meji.


No comments:

Post a Comment