Ajo-isokan agbaye bebe fun atileyin akitiyan egbe-alaanu lorile-ede Naijiria - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Saturday, 23 September 2017

Ajo-isokan agbaye bebe fun atileyin akitiyan egbe-alaanu lorile-ede Naijiria

Ajo-isokan orile-ede agbaye ti se odiwon iye atileyin ti ajo-agbaye niloo lati satileyin fun egbe allanu lorile-ede Naijiria ati ekun Lake Chad, nibi ti ogunlogo awon eniyan ti niloo iranlowo pajawiri
Labe alaga akowe agba tio n ri si oro egbe alaanu, Mark Lowcock soro yii nibi ipade apero gbogbo-gbo awon ti oro kan pe, o je ohun edun okan lati ri bi awon omo-ogun olote Boko Haram se ba ekun naa je to.
O salaye pe,”A le se, a si gbodo ran ogoro awon eniyan ti laasigbo ohun ti so di alainile-lori, ati awon ti o gba awon ti laasigbo naa le mora ni ekun ohun.”
Lowcock ti o tun je alakoso egbe ti o se iranlowo pajawiri labe ajo UN ohun se abewo si orile-ede Niger ati Naijiria ni bere osu ti a wayii lati se igbelewon akoba ti laasigbo ohun se ni ekun Lake Chad, eyi ti o so pe, o to milionu metadinlogun awon eniyan ti won fara gba isele naa.
O so pe, ni orile-ede Niger awon eniyan ti won ko ri ounje je n lo bi milionu meji, ni eyi ti awon omode ti iye won to egberun lona egberin ni ko ri ounje asara lore je, nigba ti awon eniyan egberun lona marundinlodin-nirinwo, yala ni won ko nile-lori, tabi ti won sa kuro lorile-ede Naijiria.
Gege bi oro re, bilionu kan o le owo dola ti a bere fun, fun orile-ede Naijiria, iko mejidinladota ninu ida ogorun pere ni a ri.
Lowcock so pe,“Lapapo, a ti dekun iyan, amo, a ko le dawo duro tabi fi fale rara. A gbodo ma seranwo lati ri daju pe, ogunlogo eniyan ko gbodo segbe latari airi ounje je.”
Igbakeji akowe agba ajo-isokan agbaye Amina Mohammed fi mule pe, lati bi odun mejo seyin ni orile-ede Cameroon, Chad, Niger ati orile-ede Naijiria ti n foju wina awon omo-ogun olote Boko Haram.
Igbakeji ohun so pe, awon orile-ede ti won wa ekun naa n koju awon omo-ogun alakatakiti, eto oro-aje ti o denu kole ati bi owo ori epo-robi se ja kule.
O se lalaye pe, “Mo dagba ni ilu Maiduguri, nibi ti awon omo-ogun olote Boko Haram fidi kale si, mo mo daju saka pe, ko si omo ti a bi ni olote, o ni awon nnkan ti o sokufa iwa laabi naa.”
O fi kun oro re pe, “ijoba gbodo wa woroko fi sada lati wa iyanju si ohun ti o n sokunfa laasigbo, lara eyi ti a ti ri: oro oselu, eto oro-aje esin ati awon ohun miiran”.

Amina Mohammed so pe, erongba odun 2030 je irin-ise idagbasoke ti a ni, eyi ti o je erongba metadinlogun ti awon adari lagbaye fowo si ni odun 2015, pelu iyanju ati fopin ise ohun osi, ti yoo se adinku eto aidogba ati ti yoo gbogun ayipada oju-ojo.

No comments:

Post a Comment