Ajo NEPAD wase fawon obinrin ati odo ni igberiko - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

ADS


Thursday, 21 September 2017

Ajo NEPAD wase fawon obinrin ati odo ni igberiko

Alase ati oludari Ajo idagbasoke ile Adulawo to ni ajosepo tuntun NEPAD, Gloria Akobundu ti kede pe ajo yii ti setan lati sise papo pelu awon obinrin ati awon odo ki idagbasoke le de ba igberiko kaakiri
Abileko Akobundu soro yii nibi apero pelu awon oniroyin to pe nilu Abuja pe:
‘‘A ti sise papo lati mu idagbasoke ba awon ise akosemose kookan ti won ti kuro ni erongba okan wa lati nkan bii odun kan seyin. Bayii ati n seto lorisiirisi sile fun ona lati wa ojutu si airi-sese kaakiri orile-ede bii Naijiria. A ti seto ona ipese ohun jije ati ise fawon obinrin ati odo nigberiko ki a le si oju won si awon ise to ye ni sise ti yoo je ki won nise gidi lowo ti o too gbo bukata bii ti eto CAADP to je ti ajo isokan ile Adulawo fun idagbasoke ise agbe ati ipese ounje. Eyi wa nibamu pelu erongba ijoba orile ede Naijiria fun idagbasoke de ekun mefeefa”
Ifilole eto tuntun ti NEPAD fun ipese ise fawon obinrin ati odo yii je ti ajo isokan ile Adulawo pelu erongba lati so ise di afieyin ti eegun n fiso ki idagbasoke le joba.

No comments:

Post a Comment