Alaga egbe oselu APC: Naijiria yoo duro nisokan ni - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Tuesday, 19 September 2017

Alaga egbe oselu APC: Naijiria yoo duro nisokan ni

Alaga egbe oselu All Progressives Party to n tuko orile-ede Naijiria lowolowo, Ogbeni John Oyegun ni isokan Naijiria ko ni pin nitori pe gbogbo isele to n sele bayii lori eleyameya ko ni ba nkan je mo.
Ogbeni Oyegun soro yii nibi apeje idanilola ti awon ore se fun un nibi eto awon akekojade lati fafiti akoko ni Naijiria to je ogba eleranko nIbadan ti won fi sami ayeye odun kejidinlogorin re lori oke eepe nilu Abuja.
O ni: “Lai naani awon nkan to n koju Naijiria lowolowo pe awon kan fe pin labe akoso aare Mohammodu Buhari, sibe ipile Naijiria yii yoo duro. A seleri ayipada sugbon awon kan n niwa lara nipa gbigbogun ti ise ayipada ti a n se bayii. Ijoba aare Buhari n sise lati di orile ede yii mu nisokan, Buhari je olooto eniyan ti kii segbe fenikan. Agbara okunkun ko ni I bori alaagfia orile ede yii lailai. Naijiria kii se orile ede kekere rara, a mo pe ayipada kii se ise to rorun, o maa na ni ni ekun die, ebi die ati aini die sugbon ti a ba ni suuru, didun losan yoo so nigbeyin.
Älaga eto ayeye apeje naa, Gomina ipinle Anambra nigba kan ri, Asofin Jim Nwobodo pe fun alaafia fawon toro kan kaakiri orile ede yii. O ni ki olori elesin kookan ati ile eko kookan tubo polongo alaafia ni agbegbe wa.

No comments:

Post a Comment