Awon Alatileyin Kenyatta Seto Ifehonu-han Ni Ilu Nairobi - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Thursday, 21 September 2017

Awon Alatileyin Kenyatta Seto Ifehonu-han Ni Ilu Nairobi

Awon alatileyin aare Uhuru Kenyatta  seto ifehonu-han niwaju ile-ejo giga to wa ni ilu Nairobi
Iroyin ro o wi pe. Awon alatileyin ohun fesun kan adajo ile-ejo giga naa pe, o ji ibo ti won fi jawe olubori.
Awon adajo oun fagile esi ibo aare naa ti o waye lojo-kejo osu kejo odun ti a wa yi, latari esun latodo awon ara-ilu pe,kudie-kudie ati aisiotito wa ninu eto idibo ohun.
Won fi esun kan awon adajo meji ti won dibo lati fagile le abajade esi-ibo naa Philemona Mwilu ati Isaac Lenaola pe, won  se ipade pelu awon agbejoro adari egbe oselu alatako Ralia Odinga, lasiko ti igbejo, eyi ti won fi pe aare Kenyatta nija lori jijawe olubori re n lo lowo.
Awuye-wuye ohun, eyi ti o je ijiroro gboogi laarin awon omo orile-ede Kenya lori ero kalekako so pe, eri ti o daju fi mule ninu ero alagbeka pe, awon adajo oun ba awon agbejoro egbe-oselu alatako soro.
Iroyin so pe,won ti fi iwe ipejo sowo si ajo ti o n ri si ejo kotemilorun, eyi ti yoo seayewo ati iwadii lori awon esun ti won fi kana won adajo naa.

No comments:

Post a Comment