Awon Asofin orile-ede Uganda Fija-peeta lasiko Ijiroro lori Gbedeke Ojo-ori Aare - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Saturday, 30 September 2017

Awon Asofin orile-ede Uganda Fija-peeta lasiko Ijiroro lori Gbedeke Ojo-ori AareIle-igbimo asofin orile-ede Uganda daru, lataari ijiroro kan to ni-i-se pelu gbedeke ojo-ori eni ti o ba je aare lorile-ede naa.
Ile-ise iroyin kan lorile-ede Uganda sapejuwe isele ohun gege bi eyi ti o buru-jai, ti o si tini-loju jojo, latari bi awon asofin ohun se woya-ija, ti won si n ju aga funra won.
Olori ile-igbimo asofin naa, agbenuso Kadaga fowo si oro to n ja rain-in rain-in nile pe, won ti fagile gbedeke ojo-ori aare naa.
Idaru-dapo gba ile-igbimo naa latari awuye-wuye kan pe, omo ile-igbimo asofin kan ni ibon nikawo re, ni eyi ti agbenuso naa pase fun awon eleto-aabo lati se awari ibon naa.
Awon asofin omo-egbe oselu alatako wo ile-igbimo asofin ohun pelu fila pupa lori won ati ifunpa ni apa won, eyi ti agbenuso naa so fun won  pe,  ki won yo gbogbo re kuro ki ijoko ojo naa to bere.
Ifehonu-han bere niwaju ile-igbimo asofin naa, lori ipinni fifagile gbedeke ojo-ori naa, eyi ti apa kan ninu omo egbe-oselu to wa lori alefa National Resistance Movement (NRM) se agbateru re.
Ipinnu kan waye ni nnkan bi ose meloo kan seyin, eyi ti yoo faye sile fun eto ijiroro lori fifagile gbedeke ojo ori aare lorile-ede naa, eyi ti gbedeke ohun duro lori omo odun marundinlogorin,amo won sun eto ijiroro ohun siwaju lose to koja, lagbami ogoro awon olopaa ti won da si ile-igbimo asofin naa
Ni bayii, ti won ti fagile gbedeke ohun, eyi je igbese kan Pataki lati faye gba aare to wa lori alefa Yoweni Musevei lati tun dije ninu eto idibo ti o bo.
Ni odun 2005, atunto ba iwe ofin orile-ede Uganda, ninu eyi ti won ti yo gbedeke saa meji kuro fun aare, ti yoo tun faye gba aare naa lati dije fun saa keta,eyi ti o ti jawe olubori ninu eto idibo ti o waye ninu osu keji odun ti o koja, bo tile je pe, awon egbe oselu alatako ko ri nnakan se si eyi.
Aare Museveni ti o je omo odun metaleladorin bayii, yoo fi odun meji koja gbedeke odun marundinladorin ojo-ori ti ofin la kale lati dije,  bi o ba fi maa di asiko eto idibo aare miiran ni orile-ede Uganda ni odun 2021.

No comments:

Post a Comment