Awon asojusofin satileyin fun kikopa awon odo Adulawo ninu iselu - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

ADS


Saturday, 30 September 2017

Awon asojusofin satileyin fun kikopa awon odo Adulawo ninu iselu
Ile igbimo asojusofin ile Naijiria ti tepele mo ipinnu re lati se awon abadofin to faramo pe ki awon odo tubo kopa ninu iselu ki idagbasoke to ye le deba ile Adulawo lapapo ki opin de ba ise ati osi.
Aare awon asoju nilu Abuja, Bukola Saraki lo so eyi di mimo lasiko to n si ipade awon odo ile Adulawo nilu Abuja.
Saraki ni: Gege bi koko apero yii se so lori nini awujo alaafia paapaa fifopin si sisegbe fenikan. iyanje, ise ati osi je ipa ti awon odo le sa fun ona abayo. Ise po fun awon odo.”
Agbenuso fun ile igbimo asofin kekere, Yakubu Dogara naa ro awon odo ile Adulawo lati je ohun eelo fun itesiwaju ninu iselu ati eto oro aje lapapo.
Dogara ni: Ijoba nise lati se lati seto ilana ati abadofin to ye fun idagbasoke awon odo ki a si je ki awon odo tubo kopa ninu iselu sii.”
Alaga iko apero naa ni Naijria Ogbeni Raphael Igbokwe ni awon agba ile Adulawo gbodo ji giri si ona abayo fun pipese awujo alalaafia ati oro nibi ti awon odo ko ti ni ri akoba lori ikolu orisiirisii to n lo nile Afrika bayii.
Orile ede ile Adulawo mokanlelogun bii Nigeria, Algeria, Burundi, Namibia, Niger, Swaziland, Lesotho ati Chad lo kopa ninu eto naa.

No comments:

Post a Comment