Haftar sepade pelu Sassou Nguesso lati wa iyanju si laasigbo orile-ede Libya - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

ADS


Wednesday, 20 September 2017

Haftar sepade pelu Sassou Nguesso lati wa iyanju si laasigbo orile-ede Libya

Olori alatako lorile-ede Libya Khalifa Haftar, ti sepade pelu akegbe re, aare Denis Sassou Nguesso  ti orile-ede Congo nilu Brazzaville, nibi ti ireti wa wipe ajo ile Afrika yoo wa iyanju si laasigbo to n waye lorile-ede Libya.
O se abewo si orile-ede Congo lojo abameta(Saturday), leyin ose kan ti igbimo ajo  ile Afrika se ipade lori oro orile-ede Libya, eyi ti aare orile-ede Congo, Sassou Nguesso se alaga re.
Olori orile-ede Libya, ogbeni Haftar so fun awon oniroyin leyin ipade ohun pe “Ajo ile Afrika se olulaja, eyi ti mo ro pe o je ojuse lati ran awon omo orile-ede Libya lowo, yato si awon olulaja lati awon orile-ede ile okere ti won n laja, lataari anfani tara won nikan lai ronu anfani ti orile-ede Libya.
O fikun oro re pe, bio ti le jepe, awon orile-ede ile okere n se iran lowo fun wa, amo awon omo orile-ede Afrika nikan ni o le yanju isoro ti o n koju awon omo ile Afrika fun ra won.

Haftar, ti je ki ese awon omo-ogun rinle ni orile-ede Libya, lati ibere odun ti o koja, ni eyi ti o si ko atileyin awon omo-ogun ajo isokan orile-ede agbaye nilu Tripoli ti n se olu-ilu orile-ede naa.
Akitiyan awon ajo agbaye lati wa iyanju si laasigbo oloselu lorile-ede naa ninu ipade ijiroro alafia mejeeji ti o waye laarin olori egbe oselu alatako ohun, Haftar ati ogbeni Fayez Seraj, ni ilu Abu Dhabi ninu osu karun un ati nilu Paris ninu osu keje so eso rere.

Lati gbati ipade ohun ti waye ni ilu Paris, awon omo-ogun ogbeni Haftar ti n dun koko lati wo ilu Derna ti o wa ni apa ila-orun, lati pese abo ti o peye kaakiri ilu naa.

No comments:

Post a Comment