Iko agbaboolu orile-ede Naijiria pegede sipele keji asekagba idije WAFU - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Tuesday, 19 September 2017

Iko agbaboolu orile-ede Naijiria pegede sipele keji asekagba idije WAFU

Iko agbaboolu Super-Eagles keji ti orile-ede Naijiria, lana ti fagba han iko agbaboolu orile-ede Ghana keji, pelu ami ayo meji sodo(2-0), lati pegede sinu ipele keji asekagba idije WAFU, eyi to n lo lowo nilu Cape Coast, lorile-ede Ghana.

Anthony Okpotu ati Peter Eneji Moses, se gudu-gudu meje ohun yaya mefa ninu ifesewonse naa, leyin ti awon mejeeji gba ami eye agbaboolu ti o ta yo julo ninu ifesewonse ohun.
Ifesewonse ohun lo fara han pe, iko agbaboolu orile-ede Naijiria ni lati jawe olubori ninu ifesewonse naa, lati le tesiwaju ninu idije ohun.
Pelu jijawe olubori ninu ifesewonse naa, iko agbaboolu orile-ede Naijiria bosi ipo keji ninu ate idije naa, ti iko agbaboolu orile-ede Ghana si wani ipo akoko, lataari bibori ninu awon ifesewonse meji ti won ti gba seyin.
Bio ti la jepe, iko agbaboolu iko mejeeji ko gba ami ayo Kankan wole ninu saa akoko ifesewonse ohun, ni saa keji iko agbaboolu orile-ede Naijiria fakoyo, ti won si se daradara.
Atamatase agbaboolu orile-ede Naijiria, Okpotu gba ami ayo akoko wole niseju mejilelaadota saa keji ifesewonse naa, ti Moses  si gba ami ayo keji wole niseju marundinlogota ti o pe si ra won rara.

Ni bayii, iko agbaboolu orile-ede Naijiria yoo ba iko agbaboolu ti o ba yege ninu ipele keji gba.
Gege bi akonimogba agba iko agbaboolu orile-ede Naijiria, Yusuf “ a n gbaradi fun awon ifesewonse wa daradara , besini a ni afojusun ti wa naa ninu idije WAFU, gege bi mo se so teleri, a n fi idije WAFU gbaradi fun idije CHAN to n bo lona.

No comments:

Post a Comment