Iyawo Gomina ipinle Eko n pe fun irogunsawon obinrin lapa - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Saturday, 30 September 2017

Iyawo Gomina ipinle Eko n pe fun irogunsawon obinrin lapa
Abileko Bolanle Ambode to je iyawo gomina ipinle Eko ti ni pataki ki a rogun sawon obinrin orile ede yii lapa ti di dandan ninu isejoba laye ode oni ti a ba n fe idagbasoke.
Abileko Ambode lo soro yii lasiko ti won n seto irogunsapa awon obinrin to je iyawo awon osise ipinle Eko COWSLO pe: ”O di dandan ki obinrin maa ko nipa ise inu ile ati ise ojumo ati ise awon akosemose sii loorekoore ki awon idanilekoo naa le so obinrin ile Naijiria di obinrin rere loode oko koowa won. A ni erongba pe kikoraeni se pataki ki onikaluku tun ara e ko loorekoore ki o le maa goke agba sii ninu ise ti koowa yan laayo.”
Awon koko idanilekoo lorisirsii bii: nini ajosepo to dan moran lawujo, ona idanilekoo lori ona ibanisoro, ibowo funra eni ati eto aabo ni won se nibi eto ohun.
Adele komisona fun olopa nipinle Eko, Ogbeni Imohinmi Edgal bawon soro lori ogbon idaabobo ara eni pe: “ Mimo ofin ati ilana awujo maa n je ki obinrin ri oju rere sii; mimo ona orisii lati daabobo ara eni paapaa lasiko yii naa se pataki fun gbogbo osise kaakiri laiyo obinrin sile ninu okowo won ati ninu iselu”
Aya gomina Ambode fi da awon olukopa loju pe ijoba ati igbimo naa yoo maa satileyin to ye nigba gbogbo fun awon obinrin ninu ijoba labe idari oko re ki awon ara ilu le tubo janfaani igbe aye alaafia lasiko isejoba alagabada yii

No comments:

Post a Comment