Omo milionu metalelogbon yoo gba abere ajesara ni Naijiria - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Tuesday, 19 September 2017

Omo milionu metalelogbon yoo gba abere ajesara ni Naijiria

Ajo to n mojuto oro eto ilera alabele kariaye ni Naijiria NPHCDA ni o kere tan omo to le ni milionu metalelogbon ni yoo gba abere ajesara fun aisan igbona laarin odun 2017 si 2018 ninu ipololngo MPV.
Onisegun oyinbo Joseph Oteri to je alaga apapo fun ajo yii lo so eyi di mimo nibi eto ipolongo to se pelu awon akoroyin nilu Abuja pe: “Ajo yii yoo seto abere ajesara yii ni ojule si ojule yato si ti ipolongo ori afefe ti a n lo tele. O le ni igba din mewaa milionu isele igbona to sele lodun 2014 paapaa lapa oke oya orile ede yii ni eyi to ti sun soke si milionu meta din logbon le ni eedegbeta lodun 2016. Eyi di apero fun gbogbo agbaye lapapo ni eyi to bi ki won maa wa ojutu si ona lati din isele igbona ku. Igbese ojule de ojule yii yoo je ki awon omo to to ida marundinlaadorun ri abere naa gba lasiko.
Alase ati oludari ajo yii, Onisegun oyinbo Faisal Shuaib nijoba apapo ti setan lati sise takuntakun lati mu edinku ba isele igbona laarin awon ewe wa laarin awon omo oojo si omo osu mokan dinlogota.
Abileko Margaret Soyemi to je osise pelu ajo UNICEF ni Naijiria wa lara awon orile ede agbaye to n ni isele igbona to poju lo bayii. O ni Naijiria lo tele India to nisele milionu meta todin logorun un pe ki Naijiria sise sii lati je ki awon eniyan mo nipa ipolonge bi o ti ye.

No comments:

Post a Comment