Orile-ede Congo Pe fun Ijiroro Ni Awon Ekun Ti Laasigbo Ti n Waye - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Thursday, 21 September 2017

Orile-ede Congo Pe fun Ijiroro Ni Awon Ekun Ti Laasigbo Ti n Waye

Aare orile-ede Democratic Republic of Congo, Joseph Kabila se ipade ijiroro alaafia lojo-isegun (Tuesday) ni ekun Kasai.
O le ni egberun meta awon eniyan ti won ti padanu-emi won, nigbati awon eniyan ti won le ni milionu kan ti di alainile-lori ni ekun Kasai ohun.
Iroyin ro o pe, aare Kabila se abewo si ekun naa lojo-aje (Monday) pelu olori orile-ede naa Bruno Tshibala.
Aare Kabila so pe,”alaafia se Pataki, lai si alaafia idagbasoke ko le waye”.
Ireti wa pe, awon adari ekun Kasai yoo kopa ninu ipade ijiroro olojo meji naa.
Awon alase se lalaye pe, koko ohun ti o fa sababi laasigbo ati ona abayo si isoro ohun ni won yoo jiroro le lori.
Minisita kan lorile-ede ohun Claudel Lubaya so pe, oun ko ni kopa ninu ipade ijiroro naa, nitori pe, ipade apero egbe-oselu ni yoo dale lori.
Bakan naa, olori egbe-oselu kan gboogi Le Rassemblement (The Rall), ko ni kopa ninu ipade ijiroro naa.

No comments:

Post a Comment