Orile-ede Zambia bere igbaradi fun ifesewonse pelu iko agbaboolu orile-ede Naijiria - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Tuesday, 26 September 2017

Orile-ede Zambia bere igbaradi fun ifesewonse pelu iko agbaboolu orile-ede Naijiria

Iko agbaboolu Chipolopolo ti orile-ede Zambia ti bere igbaradi ni kikun fun ifesewonse ipegede boolu afesegba lagbaye todun 2018 lorile-ede Russia, eyi ti yoo waye laarin ikon ohun ati iko agbaboolu Super Eagles ti orile-ede Naijiria, lojo keje inu osu kewa  odun ti a wa yii, ni papa isere Godswill Akpabio, ni ilu Uyo.
Gege bi atejade ori ero igbalode ayelujara Facebook ti egbe agbaboolu orile-ede Zambia FAZse so lana ojo aje(Monday),” awon agbaboolu wa ti wa ni se pe bayii, besini, igbaradi ti n lo ni kikun fun ifesewonse ohun.”
Awon agbaboolu ti ko kopa ninu igbaradi akoko ti iko ohun lojo aje(Monday) ni Simon Silwimba, Fackson Kapumbu (Zesco United), John Ching’andu (Zesco United FC), Augustine Mulenga (Zanaco).
Bakan naa, ni awon agbaboolu ti o n kopa ni ile okere, ni ireti wa pe, won yoo darapo mo won lojo aiku(Sunday).
Awon agbaboolu ikon ohun ti o ti wa ni ipago bayii ni
Awon amule: Toaster Nsabata (Zanaco), Allan Chibwe (Power Dynamos), Kelvin Malunga (Nkana FC).
Awon agbaboolu owo eyin: Adrian Chama (Green Buffaloes), Muchindu Boston, Moses Nyondo (Nkana FC), Webster Mulenga (Red Arrows), Isaac Shamujompa (Power Dynamos),Ziyo Tembo (Zanaco FC)
Awon agbaboolu owo arin: Donashano Malama (Nkana FC), Kondwani Mtonga, Mischeck Chaila, Ernest Mbewe, Augustine Mulenga (Zanaco), Godfrey Ngwenya, Larry Bwalya (Power Dynamos), Jack Chirwa, Mike Katiba, Diamond Chikwekwe (Green Buffaloes)
Awon agbaboolu owo iwaju: Simon Silwimba, Fackson Kapumbu (Zesco United), Adrian Chama (Green Buffaloes), Muchindu Boston, Moses Nyondo (Nkana FC), Ziyo Tembo (Zanaco FC), Webster Mulenga (Red Arrows), Isaac Shamujompa (Power Dynamos).

No comments:

Post a Comment