Won ro Naijiria lati din awon ilana ofin kiko ounje jade ku - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Tuesday, 19 September 2017

Won ro Naijiria lati din awon ilana ofin kiko ounje jade ku

Ogbeni Ken Ayere to je omo Naijiria olokowo to fi ile South Africa se ibujoko ti ro ijoba apapo lati din awon ofin to ro mo kiko ohun jije jade ki o le rorun fawon eniyan to je olokowo.
Ayere to je aare egbe awon omo Naijiria nile okeere tele, to tun je okan ninu awon omo Naijiria to nile ounje ni South Africa, eyi to pe ni Home Baze, eyi to si lati odun 2003 nisoro lori titete ri ounje ile wa jade. O ni: Ä ni isoro riri ounje ko wole ni South Africa, a n ko ogede wole lati ile America ni, a n ko isu wole lati Ghana ni. Dide awon ofin yii yoo je ki o tubo rorun fawon to fe se okowo kiko ohun jije wole kaakiri. A n fe isu, ogede, ata, igbin, epo pupa ati awon ohun jije miran. Ise tijoba sese bere lori kiko isu wole je igbese to dara pupo eyi to dun mo awa omo orile ede yii nile okeere ninu.
O ni oun woye pe awon omo ile Adulawo lo n jeun nile ounje awon iran miran lo sokunfa sisi ti oun sile ounje oun. O gba pe a nilo iranlowo lodo ijoba ki ounje le po fawon omo orile ede yii to file okeere se ibujoko.

No comments:

Post a Comment