Won ti parowa fawon olori nile Adulawo lati fi kun isuna-owo fawon akoroyin - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Tuesday, 19 September 2017

Won ti parowa fawon olori nile Adulawo lati fi kun isuna-owo fawon akoroyin

Won ti parowa fun awon olori orile-ede Naijiria lati tubo pese owo iranwo fawon oniroyin ni orile ede kookan nile Adulawo ki won le sise won bi o ti ye ki won le wa ojutu sisoro to m ba ekun Adulawo finra.
Omowe Soheir Othman to je olukoni ni eka ibanisoro ni fafiti Cairo lo soro yii lasiko ti won n seto ikoni eyi ti awon igbimo alakoso eto iroyin sagbekale re ni Cairo ni orile ede Egypt.
O ni eyi ni yoo je ki o rorun fawon akoroyin lati footo inu sise ki won si fon rere igbe aye alaafia bi o ti ye pe: Ïse akoroyin fun gbogbo eniyan ko rorun rara sugbon laisi ipese owo iranwo to ye lasiko ko ni si koriya fawon osise. Mo gba pe ti a ba n seto owo ninu lona ti o to ti kaluku n fife ati ooto inu sise, o di dandan ki iroyin asiko te awon ara ilu lowo lasiko. Ti awon akoroyin ko ba jabo bi o ti ye, ki won soju abe niko fawon olori won ko ni je ki onikaluku mo ibi to ku si ninu isejoba re ki won si dari ilu pelu ooto inu ni eyi ti ko ni je ki a ri ojutu sisoro ti a n koju nile Afrika”

Orile ede meedogun lo n kopa ninu apero ati idanilekoo to n lo lowo ni Cairo ni orile ede Egypt.

No comments:

Post a Comment