America yoo na aadorin le logorun un milionu dola fun ipese abere ati oogun Ebola - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Tuesday, 3 October 2017

America yoo na aadorin le logorun un milionu dola fun ipese abere ati oogun Ebola


Ijoba orile-ede America ti ni oun yoo na owo dola to to aadorin le ni ogorun un milionu lori ipese abere ajesara ati oogun arun Ebola lati pese iranwo fun oogun Ebola tuntun meji ti won n sise le lori fun itewogba lawujo.
Eka to n se iwadii lori idagbasoke ipese oogun ati ajesara, BARDA ni eka ilera atise awon ara ilu lo soro yii lojo Eti pe won yoo ra oogun ati abere ajesara wonyi tise ba pari lori won tan fun fifipamo fun lilo lati daabo bo awon eniyan ile America lasiko ti arun yii ba tun be sile.
Lara abere ajesara naa ni eyi ti won fe ra lowo ile ise apoogun Merck and Co ati Johnson and Johnson pelu Mapp Biopharmaceutical pelu Regeneron Pharmaceuticals
Oludari BARDA, Ogbeni Rick Bright ni won tete n sise lori oogun yii lataari Ebola to be sile niwo oorun ile Adulawo lodun 2014 si 2016 ni eyi to ba awon to to egberun lona ogbon eniyan ni eyi ti egberun mokanla je Olorun nipe si. Arun Ebola maa n mu eebi, iba, igbe orin ati eje dida lara dani ni.
O ni:”Loni, a pinnu lati wa oogun ati abere ajesara merin mo ohun ti a ni nile tele, eyi to yato si odun meta seyin ti ko tile si nkankan nile. Ajosepo ile America ati awon ile ise aladani pelu ijoba lo bi eso rere yii. Ninu adehun yii, BARDA yoo pese owo iranwo fawon ile ise yii ki o le tete ya ni sise sita lopo yanturu ati kise iwadii le tete dopin lori e. Ki BARDA le ri i ra lasiko pajawiri fun lilo.
BARDA yoo na milionu marundinlaadota owo dola fun awon oogun igbogunti eyi ti Mapp Biopharmaceutical yoo lo fun iwadii ati ayewo won ni America lara awon ajihinrere ti won kagbako arun Ebola nile Afirika ti won gbe wa sile fun itoju. Regeneron yoo ri o le die ni milonu ogoji owo dola gba lati fi pari iwadii oogun itoju naa.

No comments:

Post a Comment