Boko haram: America kede iranlowo milionu merinlelaadota dola fun Naijiria atawon mii - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

ADS


Tuesday, 3 October 2017

Boko haram: America kede iranlowo milionu merinlelaadota dola fun Naijiria atawon mii

Orile-ede America ti kede ipese iranlowo owo to to milionu merinle laadota owo dola fun orile-ede Naijiria, Cameroon, Chad ati awon merin miran ti won n jagun awon onise ibi Boko haram lowo.

Ogbeni Thomas Shannon Jr, to se akowe agba fun eka oselu ile okeere fun ile America lo se ikede yii nibi apero kan ni Naijiria eyi ti won pe akori re ni: Naijiria: idojuko ati ipenija wiwa alaafia eyi ti ajo alalaafia ile America ni Washington DC se agbateru re.
Shannon ni lati odun 2015 nile America ti n pese owo iranwo pe:  Lori eto aabo, Naijiria je olori rere nipa fifowosowopo pelu awon orile-ede to ku bii Chad lati gbogun ti awon ISIS iwo oorun ile Adulawo ati Boko haram. America ri awon igbese akoni yii ni eyi to je ki ijoba ile America pinnu lati ran ekun naa lowo pelu owo yii lose to koja ti o fi di milionu lona eedegbeta owo dola ti won ti na laarin odun meji seyin. Ipade mi pelu minista fun oro ile okeere Naijiria lose to koja pelu ibeere awon gomina ipinle ariwa ti won n beere fun iranlowo ile America lodun 2016 fihan pe ise gidi lo wa niwaju lati se fun ipese eko iwe ati imo kikun lori oselu tiwantiwa lati koju isoro eto aabo naa. Naijria naa ti mo pe ologun nikan ko lo le gbogun ti awon agbesunmomi yii bi ko se pelu imo lori eto ara ilu ati sise lodi siwa tani o mumi ti ko fe je ki o rorun fun wa lati ran Naijiria lowo tele.”
O ninu oun dun bayii pe ifowosowopo ti n bi eso to ye laarin awon olori elesin, ologun, oloselu, akoroyin, atawon ajajagbara fun eto ara ilu lati je ki oye tubo ye awon eniyan sii lori gbigbogun ti awon onise ibi lawujo.
Shanon fidunnu han loruko ile America lori ona alaafia ti minista ile okeere salaye fun un nibi ipade isokan agbaye to waye lose to koja pe won n gbe lowo ni Naijiria pelu idupe lowo ajo naa fun iranlowo ti won n pese fun alaafia Naijiria atifaraenijin awon osise eleto aabo.

No comments:

Post a Comment