Bukola Saraki: Naijiria yoo si wa nisokan sibe - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Tuesday, 3 October 2017

Bukola Saraki: Naijiria yoo si wa nisokan sibeAare awon asojusofin ni Naijiria, onisegun oyinbo Abubakar Bukola Saraki, ti ranse ikini ku oriire sawon eniyan Naijiria fun ayeye odun ketadinlogota ti a gba ominira kuro lowo awon oyinbo geesi amunisin lojo kinni osu kewaa lodun 1960.
Saraki soro yii nilu Abuja pelu arowa pe ki awon eniyan orile ede yii tubo ni ife, ifarada, ati aforijin fun idagbasoke eya ati iran kookan. O ro awon olori elesin kookan, olori eya ati iran kookan pe ki won tubo fowosowopo pelu awon olori agbegbe ati lobaloba ki alaafia le joba lorile ede Naijiria.
O ni:”O ti di dandan ki a poungbe fun alaafia atisokan lorile ede yii. Nipa ifowosowopo wa ni orile-ede yii fi le goke agba ki a sora fun ohunkohun to ba le ya wa nipa. E je ki a sa ipa wa ki Naijiria le begbe pe lawujo lagbaye”
Saraki gba pe orile-ede yii tun san ju bi o ti ri lesi lo, sugbon ki a tubo gba ife laaye.

No comments:

Post a Comment