Ibugbamu Afefe Gaasi Seku Pa Awon Eniyan Mefa Lorile-ede Ghana - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Wednesday, 11 October 2017

Ibugbamu Afefe Gaasi Seku Pa Awon Eniyan Mefa Lorile-ede GhanaAgbenuso fun ile ise panapana lorile-ede Ghana, ogbeni Billy Anaglate so lojo Aiku pe, o kere tan awon eniyan mefa ni won ti padanu emi, nigba ti awon eniyan marundinlogoji si fara pa, lataari ibu gbamu kan ti o waye nibi agbegbe igbonpo-robi ni olu ilu orile-ede Ghana .
Ibugbamu  nla to waye nirole ojo-abameta (Saturday) nibi ile-igbepo ti o je ti ijoba orile-ede Ghana, ti o wa ni apa ila-oorun ilu Accra da iberu bojo si okan awon olugbe agbegbe naa, eyi ti o sokufa bi ogoro awon olugbe agbegbe ohun se sa asala fun emi won.
Ile-ise ipese epo-robi ati afefe gaasi kan ni orile-ede naa, ni o ti  sakoba  lopo igba, lara eyi ti a ti ri ibugbamu ti o waye ni odun 2015 ninu eyi ti awon eniyan bi ogoorun ti padanu emi won.

No comments:

Post a Comment