Inu mi dun lati maa ba orile-ede Naijiria sise po-Rohr - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Friday, 13 October 2017

Inu mi dun lati maa ba orile-ede Naijiria sise po-Rohr

Gernot Rohr
Omo bibi orile-ede Faranse ati orile-ede Germany, Gernot Rohr , ti o je akonimogba agba iko agbaboolu orile-ede Naijiria, ti fi idunnu re han ba yii, leyin ti o ba awon akoroyin soro pe, inu oun dun pupo lati maa ba ijoba orile-ede Naijiria sise po.
Iroyin ohun waye leyin ti akonimogba agba ohun, Rohr  ran iko agbaboolu Super Eagles lowo lati je iko agbaboolu ile Afrika akoko ti yoo koko pegede fun idije boolu afesegba lagbaye, eyi ti yoo waye lorile-ede Russia lodun 2018.
Gernot Rohr
Inu mi dun pupo lati maa sise po pelu iko agbaboolu Super Eagles: Won se ba sise po, besini won se wa pelu ni gbogbo igba, bio tile jepe, opo loni pipegede fun idije boolu agbaye ohun, yoo le fun wa, sugbon emi pelu awon iko mi jo fimopo, ti a si dira wa bi osusu owo pe, a ko ni ja awon omo orile-ede Naijiria Kule rara.”
Akonimogba agba omo odun merinlelogota ohun, ni egbe to n ri si boolu afesegba lorile-ede Naijiria NFF, gba sise losu marundinlogun seyin, O ti tuko ohun gbaa ifesewonse mewa, O jawe olubori ninu ifesewonse mefa, ti o si padanu ifesewonse kan pere.
Awon esi ifesewonse ti o ti gba seyin, Naijiria-Tanzania (1-0), Naijiria-Zambia (2-1),Naijiria-Algeria (3-1), Naijiria –Togo (3-0), Naijiria- Cameroon (4-0), Naijiria –Zambia(1-0), leyi ti o je ifesewonse ti iko agbaboolu Super Eagles fi pegede fun idije ohun.
Ifesewonse ti iko agbaboolu Super Eagles ti padanu, ni o waye pelu iko agbabooolu Bafana Bafana ti orile-ede South Afrika nilu Uyo, ninu ifesewonse ipegede fun idije boolu ile Afrika to n bo lona.

pipadanu ninu ifesewonse ti o waye pelu iko agbaboolu orile-ede South Afrika, je itaniji fun wa lati tun sokoto wa de daradara, amo ni ba yii ti a ti pegede fun idije boolu agbaye, a setan lati figagbaga ninu awon ifesewonse wa to n bo lati tun pegede fun idije boolu ile Afrika.”

No comments:

Post a Comment