Ipinle Niger fopin si adehun aadorin milionu naira ibudo afe ti Gurara - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Tuesday, 3 October 2017

Ipinle Niger fopin si adehun aadorin milionu naira ibudo afe ti Gurara

Ijoba ipinle Niger lorile-ede Naijiria ti fopin si adehun kiko ile itura nibudo igbafe Gurara eyi to je aadorin milionu naira. Ogbeni Daniel Kolo to je komisona fun asa ati irin ajo afe lo so eyi di mimo ni Minna to je olu ilu ipinle Niger lasiko to n ba awon oniroyin soro.
Kolo ni Gomina Abubakar Bello lo fase si i pe ki won ye adehun naa nibi ipade awon omo igbimo alase to waye. O ni ko si akosile adehun laarin ijoba to koja ati ile ise agbasese to n ko ile itura naa pe ki won ra ile saare to le legberun kan fun lilo funra won rara.
O ni:”Omi seleru Gurara wa fun awon eniyan ipinle naa ni eyi ti a ko fi le gba enikeni tabi ile ise kile ise kankan laaye lati ra a. Ile ise Shelter and Suit ti won ni awon fe ko ile itura ti awon yoo ni sibudo igbafe yii n tan ara won ni. Ijoba lo ni ase lori ile ibudo igbafe naa”
Kolo nijoba yoo se ipade pelu ile ise ohun lati jiroro lori sisan owo ti won ti na pada. Komisona yii ro awon eniyan lati fowosowopo pelu ijoba lati sise ni awon ibudo igbafe ipinle Niger.
Koko menuba igbese ijoba lati gba ile itura Shiroro lataari bi won se n sakoso re lona aito bayii pe ijoba ti n gbe igbese lati san awon gbese awon adari ile itura naa ki won le ra ipin idokowo won lowo won kijoba le samojuto ile itura naa bi o ti ye.

No comments:

Post a Comment