Monkeypox: ajo DCC n sise ko ma le tankale - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Wednesday, 11 October 2017

Monkeypox: ajo DCC n sise ko ma le tankale

Onisegun oyinbo Chikwe Ihekweazu, to je oludari ajo NDCC to n risi itankale arun monkey pox ti parowa fun awon eniyan Naijiria  lati ni suuru, ki won fokan bale nitori pe ijoba ti n sa ipa re ki arun yii to be sile ni Bayelsa le di afieyin ti eegun n fiso.
Ihekweazu soro idaniloju yii nilu Abuja pe iko amojuto isele pajawiri RRT ti wa ni Bayelsa bayii fun iwadii lori awon isele metala ni eyi ti awon merin ti n gba itoju to ye ti won ti da aown to ku sile laisi eni to gbemi mi rara.
O ni ti won ba ti tete da isele arun yii mo, tiru eni bee tete ri itoju gba o seese ki won laa koja laiku nitori ko tii si oogun fun arun naa.
Ihekweazu ni won ti salaye fawon osise eleto ilera nigbese to ye ki won gbe  lati ko awon afurasi alaisan soto bi o ti ye.
O ni: “Monkey pox yii dabi aisan igbona ti o tun buru ju u lo. Eniyan le koo lara eku, okere ati eran igbe lasiko ti owo ba kan an tabi ti eniyan ba je e ni eyi to le de ara enikan si ekeji gege bi o se sele ni Bayelsa .
Ihekweazu ni arun yii ko wopo pupo, lodun 1970 ni won koko rii ni Naijiria.

No comments:

Post a Comment