Osise eleto ilera Naijiria gba lati fopin siyanselodi - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

ADS


Tuesday, 3 October 2017

Osise eleto ilera Naijiria gba lati fopin siyanselodi

Egbe awon osise eleto ilera ni Naijiria JOHESU ti gba lati fopin siyanselodi olojo mewaa won. Ogbeni Biobelemoye Josiah, to je alaga apapo egbe JOHESU lo so eyi di mimo fawon oniroyin leyin ipade ti won se pelu minista fun oro ise ati awon osise, Chris Ngige nilu Abuja lojo Abameta
O ni: A o se ipade pelu awon olori alase egbe lojo Isegun to m bo ni eyi ti ireti wa pe a o fopin siyanse lodi yii leyin ipade naa lojo keta osu kewaa odun yii. NEC yoo jiroro lori adehun ti a ni bayii pelu ijoba apapo”
Ojogbon Stephen Ocheni, to je minista abele fun oro ise sise atawon osise naa ba awon oniroyin soro leyin ipade naa pe gbogbo koko to n bi egbe ninu ni won jiroro le lori pupo pelu gbendeke asiko tijoba yoo mu won se lokookan.
O ni won ti gbe igbimo kan kale ti yoo mojuto awon koko naa. Logunjo osu kesan an odun yii ni JOHESU bere iyanselodi naa lori adehun ogun tijoba apapo ko lati muse bi won se fenuko le lori tele.
JOHESU je agbarijopo awon osise eleto ilera ni Naijiria bii agbale, asona, noosi, awon apoogun ati beebeelo. Die lara ohun ti won n ja fun ni sisan owo ajemonu osise lasiko, lilo gbendeke isanwo osu kan naa to je CONMESS lati odun 2014, yiyi ojo ori ifeyinti pada lati ogota odun si odun marundinlaadorin bii tawon ile iwe giga, sisan owo igbega ti won ti je seyin ati bee bee lo.

No comments:

Post a Comment