Tinubu se atileyin fun Gani Adams lori Aare Ona Kakanfo, o kan saara si Alaafin - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Thursday, 19 October 2017

Tinubu se atileyin fun Gani Adams lori Aare Ona Kakanfo, o kan saara si AlaafinAgba oselu, Asiwaju Bola Tinubu, ti ki Aare Ona Kakanfo tuntun, Otunba Gani Adams, ku oriire oye nla naa ti Alaafin Oyo, Oba Lamidi Adeyemi sese gbe le e lori.
Opo eniyan ti ro tele pe Tinubu ko ni faramo igbese naa.
Idi ni pe won ro pe oun naa nifee si oye nla naa ni, ati pe aarin oun ati Gani ko dan moran to lati nnkan bii odun meta seyin.
Sugbon ninu leta pataki kan ti Tinubu ko si Gani, o ni oun gbagbo pe o letoo si ipo naa.
Tinubu ni akoni eniyan ni Gani, to si je pe o ti ja ija ajagbara fun ile Yoruba.
Asiwaju wa kan saara si Alaafin, to si so fun un pe gbonin-gboin ni oun wa leyin ipinnu re lori yiyan Gani sipo.
Pelu iru oro iwuri yii, opo eniyan lo gbagbo pe Yoruba ti n tun ero won pa.

No comments:

Post a Comment