Aare Buhari gboriyin fawon eniyan Naijiria lori gbigbepo ni alaafia - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Friday, 3 November 2017

Aare Buhari gboriyin fawon eniyan Naijiria lori gbigbepo ni alaafiaAare Muhammadu Buhari ti gboriyin fawon olugbe Naijiria fun ipinnu ibagbepo ni alaafia ti won n gbe ni eyi ti yoo je ki isokan Naijiria duro.
Aare Buhari soro iwuri yii lasiko ifilole ere awon omo ogun ilea ti ti owo iranwo fun iranti awon omo ogun todun 2018 fun ayajo iranti awon omo ogun to subu loju ija.
O ni: Ipinnu awon omo Naijiria lati duro ni isokan lai naani esin, eya tabi iran je ohun to too fi yangan. Nitooto ojo keedogun osu kinni odun ni a n sami ayeye iranti awon omo ogun to ti subu loju ija yato si ti ojo kokanla osu kokanla awon orile ede agbaye to ku ni iranti awon omo ogun to subu ni ogun abele ni eyi ti a ja lati si duro ni okan soso.
O ro awon eniyan Naijiria lati tubo wa ni isokan, ki won si yago fun ote atiwa ipa to le tun bi ogun abele odun 1967.
Aare Buhari lo anfaani yii lati tubo parowa alaafia fawon eniyan pe: O ye ki a maa ran ara wa leti loorekoore ohun to sokunfa ogun abele ni eyi to so opolopo emi ati dukia nu ni eyi ti a ko gbadura ko tun way emo. Mo fe ki awon omo ogun ku ise takuntakun ti won n se, won n koju awon agbesunmomi lati je ki alaafia joba lati fopin si wahala to n koju eto aabo Naijiria. O di dandan ki a dupe lowo awon omo ogun paapaa awon ti won ti ba ogun lo seyin. Mo n duro de asiko ti awon olokowo nla nla ati awon osise yoo fon rere ise awon omo ogun lagbaye paapaa fun atileyin ti won n se.
Gege bii ijoba  apapo, a n gbero lati satunse to ye si oro awon omo goun ile wa. Inu mi dun pea won igbese ti a n gbe ti n bi eso rere ni eyi to ti n je koriya fawon omo ogun lokunrin ati lobinrin. A ki awon to ti n satileyin fawon omo ogun seyin, a sim aa tesiwaju lati seto idanilekoo ati ipese ohun gbogbo to ye fun awon omo ogun kise won le tubo rorun sii.”
Aare Buhari ro awon eniyan Naijiria lati na owo iranwo si ipese owo iranwo naa fun iranti ati fifi imoore han fawon omo ogun to ti subu loju ija.
O fi milionu mewaa naira sile lati fi satileyin fun owo iranwo naa.
Ogagun agba to ti feyinti, Mansur Dan Ali to je minista fun eto aabo siso loju eegun ifilole naa pelu ipe pe ki awon eniyan mojuto awon to ti subu loju ogun ati ebi ti won fi sile. O ni siso loju eegun ami naa je okan lara awon eto fun sisami ayeye todun 2018 fun ayajo iranti awon omo ogun.
Ajosepo awon omo ogun lapapo
Dan-Ali bere fun ife ati isokan laarin gbogbo awon omo ogun lapapo. O dupe lowo aare Buhari fun sise atileyin fawon omo goun nigba gbogbo ati fawon ebi won.
O menuba idije polo agbaye to je okan lara awon eto ti won yoo fi sami ayeye naa fun idije laarin awon olukopa lati America, UK, ati India ni eyi ti won yoo fi owo ti won ba ri nibe se se itoju awon opo ti awon omo ogun fi sile.
Awon miran ti won wa nibe ni igbakeji aare Yemi Osinbajo, aare ile igbimo asofin Onisegun oyinbo Bukola Saraki, Abenugan ile igbimo asofin kekere Ogbeni Yakubu Dogara, Adajo agba ni Naijiria Walter Onnoghen, pelu gomina ipinle Adamawa, Jibrilla Bindow ati awon minista miran.

No comments:

Post a Comment