America seleri $60m lati gbogunti idun-koko moni ni Sahel Africa - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Friday, 3 November 2017

America seleri $60m lati gbogunti idun-koko moni ni Sahel AfricaIle-ise ti o n ri si oro ile okere lorile-ede America so lojo-aje (Monday) pe, orile-ede America ti seleri owo ti iye re to ogota milionu owo dollar, ni iyanju ati satileyin fun  awon orile-ede marun-un lati pawopo gbogun ti iwa idun-koko moni,
Awon apapo omo-ogun naa, ti iye won yoo je egberun lona marun lati orile-ede Mali, Niger, Burkina Faso, Chad ati orile-ede Mauritania, ni won yoo sigun mo awon alakatakiti ti won n dun-koko mo awon ekun naa ni apa iwo-orun ile Africa, eyi ti won ni nnkan se pelu omo-ogun olote ijo Al Qaeda.
Atileyin orile-ede America fun awon omo-ogun ekun mamaarun ti a mo si G5 ja kule, latodo orile-ede France ati awon miiran, eyi ti orile-ede America yoo satileyin taara owo fun latodo ajo isokan orile-ede agbaye.
Asoju orile-ede America ninu ajo UN, Nikki Haley, lasiko ti o n ba igbimo eleto abo soro pe,”a ni igbagbo pe, awon omo-ogun awon ekun marun naa gbodo wa, ti won gbodo je omo-ogun awon orile-ede lati ekun mararun naa”.
O salaye pe,”A nireti pe, awon orile-ede mararun naa yoo ni amojuto ni kikun awom omo-ogun won naa laarin odun meta si odun mefa pelu atileyin orile-ede America”.
Enikan ti ki somo igbimo eleto abo ajo UN so pe, orile-ede America n sapa re lati ri pe, ajo UN n satileyin taara fun awon orile-ede naa.
Akowe agba orile-ede America Rex Tillerson so pe, ile-igbimo asofin orile-ede America yoo jiroro lori owo ti orile-ede America jeje naa, ni eyi ti ireti  wa pe, yoo mu ajosepo to muna doko waye laarin ekun naa lati gbogun ti awon omo-ogun olote ati gbogbo ona ti won n gba se ise ibi won.
Awon orile-ede marun ohun ti se agbekale isuna owo ti o iye re n lo bi milionu marun fun ise akanse ipele akoko, ni eyi ti orile-ede America si kede atileyin re, ipade apero gbogbogbo fun ikowojo latodo awon alaanu yoo waye ni ilu Brussels lorile-ede Belgium ninu osu kejila odun ti a wa yii.

No comments:

Post a Comment