Amosun soro idaniloju lori atileyin ninu idibo 2019 fawon agba ipinle Ogun - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Sunday, 26 November 2017

Amosun soro idaniloju lori atileyin ninu idibo 2019 fawon agba ipinle OgunGomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun ti fi ye awon agbaagba ipinle Ogun pe oun ti setan lati gbe ijoba sile fun enikeni to ba jawe olubori ninu idibo 2019. O soro yii lasiko to n se ipade pelu won ni ekun iwo oorun Ogun nilu Abeokuta to je olu ilu ipinle Ogun.
O ni: “Emi ko lati wo ariwo oja lasiko yii, paapaa awon oloselu ti oro won ko ye ara ilu mo. E ma wo oludije lati ekun miran gege bi ota yin, awon eniyan wa lati ekun to ku je ore yin, awon naa de ni oore ofe lati jade gege bii oludije to ba wu won.”
Awon agbaagba ekun naa fi atileyin won han fun gomina lati duro ti enikeni to ba fa kale lati ekun naa. Won ni ki gomina gba awon eniyan ekun yii laaye lati lo asiko won lati fa enikeni to ba wun won kale gege bi oludije lati ekun ohun lodun 2019.
Odun 1976 ni a da ipinle Ogun sile lati ara ekun iwo oorun atijo ni Naijiria pelu Abeokuta gege bi olu ilu re. Won pin in si ekun merin: Remo, Ijebu, Yewa ati Egba.
Ko tii si omo Yewa to tii de ipo gomina ri latigba ti won ti da ipinle naa sile lodun 1976.

No comments:

Post a Comment