China gborinyin fun ipinnu Mugabe lati falefa sile - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Friday, 24 November 2017

China gborinyin fun ipinnu Mugabe lati falefa sileOrile-ede China so lojo ru pe, ohun bowo fun Robert Mugabe lati fi ipo Aare orile-ede Zimbabwe sile, leyin ose kan ti ile-ise ologun orile-ede naa ati alatileyin oselu Mugabe tele ri,gbe igbese ati fopin si isakoso ologoji odun Aare naa.
Omo odun metaleladorun naa faake kori lati ose kan ti awon ologun ti gba isakoso ijoba, ni bayii Mugabe ti kowe fipo sile lojo-isegun, nigba ti ile-igbimo asofin orile-ede naa n gbe igbese ati yo Aare naa nipo, eyi ti o fa idunnu ti awon eniyan si n jo kiri oju titi.
Agbenuso fun ile-ise oro okere lorile-ede China, Lu Kang so fun awon oniroyin pe, inu orile-ede China dun lati ri pe, orile-ede Zimbabwe yanju aawo won ni itunbi-inubi.
Lu so pe, “orile-ede China bowo fun ipinnu Mugabe naa, ni eyi ti yoo je ore fun awon omo orile-ede China, o fi kun oro re pe, Mugabe ti fi itan manigbagbe le le, latari sisa gbogbo ipa ati akitiyan re lati je ki orile-ede naa di olominira”.
Ile-ise ologun gbajoba, leyin ti Mugabe yo igbakeji re, Emmerson Mnangagwa nipo, eni ti gbogbo eniyan gba pe yoo gba ipo lowo re.
Ipinnu Mugabe ni lati je ki iyawo re Grace omo odun mejileladota, ti gbogbo eniyan mo si “Gucci Grace”, latari bi o se maa n ra oja lorisirisi.
Ireti wa pe, won yoo bura fun Mnangagwa laipe ojo, ni eyi ti yoo lo iwonba ojo ti o ku ki saa Mugabe pari, titi ti eto idibo yoo fi waye ninu osu kesan-an odun 2018.

No comments:

Post a Comment