Eto-isuna 2018 maa mu idagbasoke ba ekun guusu-ila oorun Naijiria - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Friday, 10 November 2017

Eto-isuna 2018 maa mu idagbasoke ba ekun guusu-ila oorun NaijiriaAlase ati oludari Ile Akede Naijiria, Voice of Nigeria, Ogbeni Osita Okechukwu ni eto isuna todun 2018 tijoba Aare Buhari gbe siwaju ile igbimo asofin lana nilu Abuja yoo mu idagbasoke ba amayederun ekun ila oorun guusu Naijiria paapaa lori atunse opopona ati awon ohun alumooni ile.
Aare Buhari gbe eto isuna to le ni tirilionu mejo naira siwaju ile igbimo asofin agba ati kekere lojo Isegun.
Ogbeni Okechukwu lo soro yii nilu Enugu pe eto isuna naa yoo je ki o rorun lati pari awon ona tise n lo lowo lori won ati ti afara Naija keji ni eyi tijoba ti ya milionu mewaa owo dola ile okeere soto.
Alase VON ni ijoba apapo ti fi bilionu merinla dola sile ninu bilionu merindinlogoji le die ti won la kale fun ise akanse naa ni eyi to fi erongba aare Buhari han lori ati tete pari ise akanse ohun.
O ni: Äare Buhari labe akoso ijoba re yii ti fi bilionu merinla ninu ogorun un milionu owo yiya Sukuk si atunse ona ekun ila oorun guusu ni eyi to fihan pe ijoba yii fe mojuto ona okowo ni ekun yii lasiko yii. Ile ise eedu tilu enugu yoo ri pupo ninu ogbon bilionu ti ijoba ya soyo fun ohun alumooni ile. O ye ki ekun yii moa won ore won nitooto bayii tijoba n nawo kekere to n ri fun idagbasoke ekun kookan.
Okechukwu ni awon eniyan Naijiria ti ria won ise akanse tijoba n se laarin odun meji yii ti o n gbero ki a si okowo kuro ninu epo robi lo si awon nkan miran.
O menuba ise akanse ti Mambilla Plateau to je ti alatagba amunawa ni eyi ti yoo je kipese ina monamona tubo po sii.

No comments:

Post a Comment