gbe-Alajeseku yoo safikun 30% sidagbasoke eto oro-aje Naijiria - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Friday, 10 November 2017

gbe-Alajeseku yoo safikun 30% sidagbasoke eto oro-aje NaijiriaMinista fun eto ogbin ati idagbasoke igberiko lorile-ede Naijiria, Oloye Audu Ogbeh ti so pataki egbe alajeseku sipinnu won lati se afikun to to ida ogbon ninu ogorun un owo to n wole ni Naijiria titi odun 2025.
Audu Ogbeh soro yii ni Minna lasiko to n siso loju eegun eto apero awon alajeseku tolojo meji ti apapo egbe alajeseku Naijiria CFN.
O fi ireti re han pe ti awon egbe alajeseku ba sise won bi o ti ye lasiko ijoba to wa lori aleefa bayii, o di dandan ki eto oro-aje bureke sii.
Audu fikun oro re pe: Öludari agba egbe alajeseku lapapo ti soro lori ipinnu egbe lati mu ida ogbon ninu ida ogorun un o pe tan titi odun 2025. Akosile ti mo ri laipe yii fihan pe o to eniyan milionu merindinlogbon ti won n sise ninu egbe alajeseku tabi ti won je omo egbe. Nigba ti o le ni ogorun un mejo milionu awon omo egbe alajesu kaakiri agbaye. “
Ogbeh sapejuwe egbe alajeseku Kenya to wa nipo keje lagbaye ati akoko nile Adulawo pelu odiwon iye won ati agbara ipin okowo omo egbe kookan ni eyi to to ida marundinlaadota ninu ogorun un iye owo to n wole ni Kenya lodun.
Gomina Abubakar Sani Bello tipinle Niger, to si eto apero naa menuba Pataki egbe alajeseku fun idagbasoke eni kookan boya oloro tabi talaka ati ti orile-ede lapapo.

No comments:

Post a Comment