Ipinle Gombe ro awon eniyan lati nifura lori Monkey pox - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Friday, 3 November 2017

Ipinle Gombe ro awon eniyan lati nifura lori Monkey poxIjoba ipinle Gombe ti parowa fawon olugbe ipinle Gombe lati sora fun awon agbegbe ti won ti fura pe isele monkey pox ti sele si. Onisegun oyinbo Kennedy Ishaya to je komisona fun eto ilera nipinle Gombe lo parowa yii lojo Isegun lasiko to n se ifitonileti ibi ti ise igbaradi de duro nipinle Gombe lori arun naa.
Bakan naa lo ro awon eniyan lati tete se ifitonileti to ba ye fun isele kisele ti won ba fura si lasiko.O ni kete tijoba ipinle Gombe ti kefin isele Monkey pox ni won ti gbe igbese to ye lori idena re.
Komisona naa ni ipese owo nina fun iru isele bee wa ninu isuna ipinle naa ni eyi ti won ti fi milionu meji sile fun lilo fun igbaradi.
O menuba okan lara igbese ti won ti gbe bii fifi aaye ipamo sile nile iwosan ijoba fun gbigba awon to ba sagbako monkey pox. Rira awon oogun ati ohun eelo sile ati siseto ipolongo kaakiri ipinle naa.
Ishaya ni ijoba ipinle Gombe ti gba lati ya milionu mejo naira sile fun rira egboogi agbogun ti oro ejo nibudo itoju oro ejo titani nijoba ibile Kaltungo. Pe ni kete ti won ba ti ko egboogi naa wole nijoba yoo kede re fun awon ara ilu.
O ni won ti lo egboogi tijoba apapo fi se iranwo sibudo naa tan nitori awon ti ejo san je lati Naijiria, Cameroun ati Chad Republic ni won n wa fun itoju nibudo naa. O safikun pe losu kokanla yii ni won yoo sibudo naa to wa fun itoju oro ejo to je onibusun aadota le ni igba.
Onisegun oyinbo Balla Abubakar to je oludari ibudo naa  ro ijoba apapo lati tubo se iranwo sii nitori ibudo naa ko gba awon eniyan mo nitori pe ko si oogun mo pe eniyan mesan an pere lo wa nile bayii ti won n ra egboogi naa funra won. Bakan naa lo ki awon ijoba ipinle naa fun fifowosi milionu mejo naira fun rira egboogi to ye ni lilo.

No comments:

Post a Comment