Minista gboriyin fun Nollywood fun idagbasoke ere onise ile Adulawo - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Friday, 3 November 2017

Minista gboriyin fun Nollywood fun idagbasoke ere onise ile AdulawoMinista fun eto iroyin ati asa fun Naijiria, Alhaji Lai Mohammed ti yombo awon egbe osere ni Naijiria ti a mo si Nollywood fun ise takuntakun ti won n se lati je koriya fun eka idanilaraya nile Adulawo.
O soro yii nipinle Eko nibi eto iside ayeye fiimu agbelewo nile Adulawo AFRIFF to je eleekeje iru re.
Lai Mohammed ni: wiwa sibi loni je lati ki awon AFRIFF ati Nollywood ku ise takuntakun ti won n se, bi mo se n wo ero yanturu yii n safihan ifokansin ati igboya lati sise ki ojo iwaju ere onise le gbounje fegbe gbawo bo nile Afrika. A bi AFRIFF lati Nollywood ki o le maa se koriya fun eka idanilaraya ki o le tun je ki ise fiimu sise rorun. Ijoba n gbiyanju pe ki owo yiya wa fun awon osise elere onise pelu owo ele to mo niwon. Bakan naa nijoba n seto kiko ibudo sinima to to ogorun un kan kaakiri orile ede yii.”
Alhaji Mohammed soro lori lilo alatagba NTA lowo ni eyi ti yoo je ki awon eniyan ni afojusun sisi po si ona igbalode ninu igbohunsafefe ni eyi ti ijoba Naijiria n sise lori eyi ti yoo fun awon eniyan to to milionu merinlelogun lati wo amohunmaworan leekana ati lati wo fiimu laira a tabi lai san owo data lori ayelujara.
Ni ipari, Minista ki awon AFRIFF ku ise ikoni ti won se fun idanilekoo awon eniyan egberun kan abo fun awon eniyan Afrika to n dide bo ninu ise fiimu sise ki idagbasoke le de ba ere onise bii ti agbaye.
AFRIFF je apejo olodoodun fawon to n se fiimu agbelewo nile ati loke okun pelu awon akosemose, awon osere, awon oludari aria won gbogbo to nii se pelu sinima.

No comments:

Post a Comment