Omo-ogun ile Naijiria bere abadofin ede Naijiria fawon omo ogun - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Friday, 24 November 2017

Omo-ogun ile Naijiria bere abadofin ede Naijiria fawon omo ogunIko omo ogun ile ni Naijiria ti bere abadofin tuntun pe gbogbo omo ogun gbodo ko bi a ti n so ede Naijiria meteeta ki won le soo ki won si moo ka ni eyi to le mu won maa gba owo ede.
Oludari eka awon alaniloye fun awon omo ogun, Ogagun Sani Kukasheka Usman fi atejade sita nilu Abuja ni pe igbese ofin dandan kiko ati siso ede miran je ohun to n sele laarin awon omo ogun lagbaye ni eyi ti won fi maa n ro awon omo ogun lati ko ede lorisiirisii.
Igbese yii yoo je ki won mo ede ati asa awon eya to ku lorile ede Naijiria.
O ni: “Eyi yoo bi isokan ati mimo ara eni sii, ti yoo si je ki won tubo gbo ara won ye sii.. Ede oyinbo ni yoo si je ede apapo nigba ti Yoruba, Igbo ati Hausa yoo je ede fun lilo ninu ise akanse awon ara ilu ti won pe ni CIMIC. A ti fun awon omo ogun ni gbendeke odun kan lati ko ede meteeta. Eyi yoo fun enikeni to le so ede meteeta ni anfaani lasiko igbaniwole sise Ologun ni Naijiria lati asiko yii lo.”
O ni tele ni won maa n ro awon omo ogun Naijiria lati ko ede miran lagbaye bii  ede Larubawa, Ede Spanish, Ede Portuguese ati Swahili pelu ede Faranse.

No comments:

Post a Comment