Super Eagles gba ojo miran fun ifesewonse ipegede idije AFCON 2019 - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Sunday, 26 November 2017

Super Eagles gba ojo miran fun ifesewonse ipegede idije AFCON 2019Ajo to n ri si ere-idaraya boolu afesegba nile Adulawo CAF  ti yan ojo keta osu kesan si ojo kokanla osu kesan odun 2018  fun ifesewonse ipegede idije AFCON 2019, ti yoo waye laarin iko agbaboolu Super Eagles ati iko agbaboolu orile-ede Seychelles.
Iroyin so pe, Ifesewonse ohun ye ko waye lojo kokandinlogun osu keta si ojo ketadinlogbon osu keta odun 2018, sugbon ti won sun siwaju lataari awon ifesewonse olorejore ti yoo maa waye lolokan-o-jo-kan fun igbaradi idije boolu agbaye ti yoo waye lodun 2018.
Ni bayii, orile-ede Naijiria, Egypt, Morocco, Tunisia ati orile-ede Senegal ni yoo lo soju ile Afrika ninu idije boolu agbaye to n bo lona lorile-ede Russia.
Ewe, iko agbaboolu Super Eagles yoo maa gbalejo iko agbaboolu orile-ede Libya ni papa isere  Godswill Akpabio  nilu Uyo, fun ifesewonse ipegede idije  AFCON 2019 ohun.
Bi o tile je pe, iko agbaboolu orile-ede Naijiria padanu ifesewonse ipegede AFCON  akoko sowo iko agbaboolu Bafana Bafana torile-ede South Afrika, iko mejeeji ohun yoo tun maa koju ara won ninu ifigagbaga keji lojo kejila osu kokanla si ogun-jo ojo kokanla osu kejila odun 2018.

No comments:

Post a Comment