Yakubu Aiyegbeni feyin ti ninu ere boolu afesegba - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Sunday, 26 November 2017

Yakubu Aiyegbeni feyin ti ninu ere boolu afesegbaAgbaboolu iko Super Eagles tele ri, Yakubu Aiyegbeni ti kede ifeyin ti bayii ninu ere idaraya boolu afesegba.
Yakubu, ti awon eniyan mo si ‘The Yak’, so eyi di mimo lojoru(Wednesday) ti o n se ayeye ojo ibi omo odun marundinlogoji.
Yakubu Aiyegbeni
Atamatase ohun, Yakubu Aiyegbeni feyin ti, leyin ti saa re bo si ipari ninu iwe isise po iko agbaboolu Coventry City ni ibere odun yii.
Bakan naa, ni Yakubu kopa fun iko agbaboolu lorisirisi lorile-ede England bii, iko agbaboolu Portsmouth FC, Middlesbrough, Everton, Leicester City, Blackburn Rovers ati Reading.
O gba ami ayo mokanlelogun wole ninu ifesewonse metadinlogota ti o kopa fun iko agbaboolu Super Eagles, eyi ti o so di agbaboolu keta ti o gba ami sawon julo fun orile-ede Naijiria.

Ni bayii, ajo to n ri si ere idaraya boolu afesegba lorile-ede Naijiria NFF,  ti para po pelu awon ololufe re jake jado lati se ikinni ku ori re ojo ibi re ti o waye lojoru(Wednesday).

No comments:

Post a Comment