Zimbabwe Reyin Mugabe: Idunnu subu layo nilu Harare - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Friday, 24 November 2017

Zimbabwe Reyin Mugabe: Idunnu subu layo nilu HarareIdunnu subu layo kaakiri ilu Harare ati awon ilu miiran ni orile-ede Zimbabwe, nigba ti agbeniso ile-igbimo asofin orile-ede Zimbabwe, Jacob Mudenda ka iwe ifipo-sile ti Mugabe ko.
Awon eniyan n jo kaakiri aarin titi nigba ti won gbo pe, opin ti de ba isakoso Mugabe, eni ti o ti n dari orile-ede Zimbabwe latigba ominira ni odun 1980.
Awon miiran gbe aworan Mnangagwa ati adari awon omo-ogun orile-ede naa, Consantino Chiwenga.
Awon osise tan ina keresimesi ni gbagede ile-isokan Afrika, ogoro awon eniyan ni won gun oko ologun ti won si n ya aworan pelu awon ologun.
Arabinrin kan Maria Sabawu so niwaju ile-itura ti igbese iyonipo naa ti waye.pe, “inu oun dun si gbogbo ohun to sele naa” .arabinrin ohun  je alatileyin egbe-oselu Movement for Democracy Change (MDC).
O salaye pe, “oun jiya pupo lowo isakoso ijoba Mugabe”. o fi owo re han pe,  oun padanu ika oun  lasiko ifehonu-han tako atundi idibo ti o waye laarin Mugabe ati olori egbe-oselu alatako, ogbeni Morgan Tsvangirai ni odun 2008,
Bi o tile je pe, idunnu subu layo fawon omo orile-ede Zimbabwe, sibe isubu Mugabe tun da lori aawo to waye laarin awon ogbontarigi oloselu naa, amo, ogooro awon eniyan ni won seto iwode tako Mugabe lojo keji ti awon ologun gbakoso ijoba orile-ede naa,
EGBE ALAAFORIJIN LAGBAYE
Egbe alaforijin lagbaye so pe, labe isakoso Mugabe ogooro awon eniyan ni won jiya manigbagbe.
Egbe ajafeto omo eniyan so ninu atejade kan pe, “awon omo orile-ede Zimbabwe ye ko gbe igbe aye irorun, awon iran adari to n bo gbodo fi ara won jin fun eniyan, ki won si bowo fun ofin, ki won si maa se awokose egbe ajafeto omo eniyan lorile ede Zimbabwe, ki won si se ojuse won fun ara-ilu bi o ti to ati bi o se ye”.

No comments:

Post a Comment