GSK bere iwadii lori oogun-bi-abeere ti yoo maa dena HIV - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Monday, 4 December 2017

GSK bere iwadii lori oogun-bi-abeere ti yoo maa dena HIV

ViiV Healthcare, to je eka kan gboogi ni ile ise GlaxoSmithKline Plc ti bere ise ni eka arun HIV fun ise iwadii nile Adulawo lori lilo oogun-bi-abere fun didena arun HIV lara awon obinrin ti won ti balaga ti won ti n ni ibalopo.
ViiV Healthcare fi atejade sita pe iwadii Cabotegravir yii yoo gba won nise iwadii lori awon igba le ni egberun meta obinrin ti ojo ori won wa laarin omo odun mejidinlogun si marundinlaadota ni awon orile-ede ile Afrika. Won ni abala akoko ni won pe ni HPTN 084 Phase111 nibi ti won yoo ti fun won labere naa fun osu meji-meji.
Ile ise naa nipese owo iranwo fun ise iwadii yii wa lati ajosepo apapo atawon aladani labe akoso ViiV Healthcare gege bi ile ise iwadii afaarun ati ajo adaduro ti kii se tijoba Bill ati  Melinda Gates Foundation.
Lodun 2016 ni Viiv Healthcare bere iwadii nla lori awon okunrin ti ko ni arun HIV atawon sakosabo obinrin ti won ti ni ibalopo pelu okunrin fun ayewo bi oogun-bi-abere naa ba n dena afaarun to n fa aisan AIDS

No comments:

Post a Comment