Ijoba mu riri ona ifetosomobibi rorun sii fawon abiyamo igberiko - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Thursday, 14 December 2017

Ijoba mu riri ona ifetosomobibi rorun sii fawon abiyamo igberikoIle ise ijoba apapo Naijiria to n risi oro eto ilera ti bere agbekale ona pinpin awon ohun ilera ati igbese eto kiko awon osise ilera alabode ni ona igbalode eyi ti yoo je ki awon eniyan igberiko maa je anfaani eto ifetosomobibi lona irorun.
Eto idanilokoo yii yoo je ki awon ti kii se agbebi naa ni imo kikun lori ona sise ifetosomobibi fawon abileko nigberiko kaakiri Naiijiria.
Ojogbon Isaac Adewole to je minista to n tuko ile ise ijoba apapo yii lo so igbese yii di mimo pe ise akanse yii yoo waye pelu ajosepo iranlowo ile ise Marie Stopes lagbaye. O ni won yoo se idanilekoo to ye kooro fawon osise ilera lori awon orisii ona ifetosomobibi to wa ati bi aa ti n se won laseyori nigberiko.
Minista naa ni ipinle Kaduna ati Ondo ni won yoo ti koko bere gege bii ipinle afojusun pe: “o ti hande pe awon osise eleto ilera ko po kaakiri igberiko rara, won ko po to fun ise to wa nile. Awon ilana aamulo ati igbese pinpin awon ohun eelo wonyii ni yoo tun je ki a bere si ni lo awon osise eleto ilera kaakiri orile-ede yii.”
Alase Marie Stopes fun Naijiria, Apoogun Effiong E. Effiong nile ise yii ti setan lati satileyin to ye fun ile ise eto ilera Naijiria lati bere eto naa nipinle mejeeji yii nipa titele ilana ti won ti fenuko le lati odun 2014.
O ni won ti se iwadii tele boya awon osise eleto ilera naa le ni imo kikun lori ona aatele lati seto ifetosomobibi alabere ati oni fifi nkan si ara abilkeko ni eyi ti abajade iwadii naa ti fihan pe won le see laini wahala Kankan.

No comments:

Post a Comment