Saudi, UAE yoo Seranwo ati gbogun-ti omo-ogun olote nile-Africa - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Thursday, 14 December 2017

Saudi, UAE yoo Seranwo ati gbogun-ti omo-ogun olote nile-AfricaOrile-ede Saudi Arabia ati United Arab Emirates n se ipade apero kan nilu Paris lorile-ede Faranse lojo-Ru, pelu erongba ati tete se agbekale awon omo-ogun ile-Africa kan lati sigun mo awon omo-ogun olote, eyi je ona ti awon orile-ede Gulf Arab ohun se le satileyin fun ekun naa.
Awon ekun marun-un ohun je, apapo awon omo-ogun orile-ede Mali, Mauritania, Niger, Burkina Faso ati orile-ede Chad se ifilole ise-akanse awon omo-ogun naa, ni eyi ti won yoo saami idasile  re ninu osu kewaa, laagbami aibale-okan ni ekun Sahel  ohun, ti awon alakatakiti elesin Islam, pelu awon omo-ogun olote Al-Qaeda n fi igba gbogbo gba enu ibode won koja.
Ewe, orile-ede Faranse ti o ni egberun merin awon omo-ogun ni ekun naa ti ke gbajare lori bi awon omo-ogun olote naa se n bori awon omo-ogun ijoba ni ile Africa, nigba ti awon omo-ogun orile-ede marun-un ohun n tiraka lati ri awon olugbowo, pelu erongba lati le sise won doju ami..
Lati le se aseyori ninu eyi, Aare orile-ede Faranse, Emmanuel Macron  yoo gbalejo awon olori orile-ede marun-un ti oro kan, olori orile-ed Germany ati orile-ede Italy, bakan naa ni minisita fun oro ile-okere lorile-ede Saudi ati ti  Emirate yoo kopa nibi ipade apero naa.
Ogoro awon omo-ogun apetusawo ajo isokan orile-ede agbaye, awon omo-ogun orile-ede Faranse ati ti orile-ede America ti won ti gbeto idanilekoo doju ami, ati awon ogbontarigi onise akanse omo-ogun oju ofurufu ti kuna lati dekun itankale laasigbo awon alakatakiti elesin Islam naa.
Asoju orile-ede Faranse kan so pe, “lati bi osu meloo kan seyin, akitiyan awon omo-ogun olote n po si, ni eyi ti awon omo-ogun apetusawo n dinku, eyi ja si pe, a gbodo gbe igbese ni kankan lati le gbakoso ekun naa, ki won si mu igberu ba akitiyan awon omo-ogun apetusawo ni ekun ohun”.
Macron safihan sise agbekale awon omo-ogun ekun naa ni kikun, lati le se akokuro awon omo-ogun orile-ede  Faranse ti won sigun mo awon omo-ogun olote ni apa ariwa orile-ede Mali ni odun 2013.
Asoju ohun fi kun oro re pe, “erongba ohun ni lati se atileyin alekun fun awon omo-ogun. eto oselu ati sise alekun owo, pelu iyanju ati se alekun awon omo-ogun naa si egberun marun-un ti o ba fi maa di osu keta odun 2018”.
Orile-ede Saudi Arabia seleri ati satileyin ogorun milionu owo dollars, eyi ti yoo se die lara edegbeta milionu owo dollars ti ekun Sahel marun-un ohun n wa, lati bere ise-akanse ipele akoko, bakan naa ni UAE tun satileyin owo fun awon ile-iwe ni orile-ede Mauritania, ti won yoo si ninu osu kinni odun to n bo,

No comments:

Post a Comment