VON, NTA ati FRCN se isin asale keresimesi 2017 laseyori - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Thursday, 14 December 2017

VON, NTA ati FRCN se isin asale keresimesi 2017 laseyoriIle Akede Naijiria, Voice of Nigeria pelu ile ise amohunmaworan NTA ati ile ise redio Naijiria FRCN saseyori isin asale olodoodun keresimesi fun todun 2017 ni gbangan National Christian Center nilu Abuja lojo Aiku.
Awon akorin emi fun ijo ologo to m bo lati ile Akede Naijiria, VON, ile ise amohunmaworan Naijiria NTA, ati FRCN korin ni orisiirisii ede Naijiria lati fi isokan orile ede yii han ati lati fi yin Olorun to si n di Naijira mu titi di isin yii nibi isin ohun.
Igbakeji Aare, Ojogbon Yemi Osinbajo ro awon eniyan Naijiria lati tun Naijiria bi labe isakoso Aare Mohammed Buhari ki won jo sise papo lati tubo gbogun ti iwa ibaje ninu Naijiria titun yii.
Olori Alufaa fun ile ijosin ile ijoba ni Aso Rock nilu Abuja, Alufaa Seyi Malomo lo soju fun igbakeji Aare nibi eto ijosin naa lati smai ayeye ibi Jesu Kristi fun igbala awon omo araye. Igbakeji Aare ni: “Asiko odun keresimesi je odun to yato pata nitori pe ohun ni a fi n sami ayajo ibi Jesu Kristi ni eyi to n ran wa leti pataki ibi Jesu fun igbala omo araye kuro ninu egun, ise, osi ati iku ayeraye. Loni ni Naijiria, itan ibi Jesu se Pataki nitori pe a maa bi ohun otun ati eso rere ni. Orile ede yii ti jiya seyin labe awon ajegudujera, ase ibaje ati anikan janpon eda, sugbon bayii ireti wa ti n dide si iran otun ati igbe aye alaafia ni eyi ti a n ro koowa lati sa ipa re lati tun Naijiria se”.
Ojogbon Osinbajo ni Naijiria kun fun awon olopolo pipe pupo ni eyi to ye ki a jo fowosowopo fi maa se ohun rere nipele ijoba ati loode koowa ki eso rere le tubo pos ii fun gbogbo mutumuwa. O ro awon eniyan orile ede yii lati tepa mose ki onikaluku gba alaafia laaye ninu okan ati ninu ihuwasi won gbogbo.
Ojogbon Osinbajo so asotele pe Naijiria si maa wa nisokan ju ti tele lo nitoripe idagbasoek nla n bo laipe ni eyi ti a maa fihan gbogbo agbaye pe opo ero maa n bi eso pupo ni ifgbega ni.
Olori ijo Foursquare Gospel Church fun gbogbo Naijiria, Alufaa Felix Meduoye ninu iwaasu re nibi isin asale keresimesi naa lo ti lo ese bibeli iwe orin Dafidi ori kokandinlogbon ese kokanla fi gbadura fun alaafia atidagbasoke fuun awon olugbe Naijria fun odun 2018.
Awon miran ti won wa josin fun Eledaa won nibi isin orin kiko fun keresimesi olodoodun naa ni olori orile-ede yii nigbakan ri, Ogagunfeyinti Yakubu Gowon; akowe agba fun Naijiria, Mustapha Boss; Asojusofin Dino Melaye atawon miran.
Ogbeni Osita Okechukwu to n tuko ile Akede Naijiria lo pin ebun fawon eekan to wa nibi isisn keresimesi naa fun yiye awon ile ise iroyin naa si ti won jo sowopo sagbekale eto orin keresimesi.
O ro awon eniyna Naijiria lati tubo maa gbadura fun isokan, idagbasoke atilosiwaju Naijiria, bakan naa lo dupe lowo Olorun fun wiwo Aare Buhari san kuro lori akete aisan re.

No comments:

Post a Comment