Agbajo JTF omo-ogun Naijiria se ifilole ise-akanse jagunlabi lati gbogunti awon aji-epo-gbe - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Monday, 1 January 2018

Agbajo JTF omo-ogun Naijiria se ifilole ise-akanse jagunlabi lati gbogunti awon aji-epo-gbeAgbajopo awon omo ogun ile, omi ati ofurufu ni Naijiria ti se ifilole ona ija tuntun ti won pe nise akanse Jagunlabi  lati gbogun ti awon ti won n ji epo robi gbe nipa biba opa to n gbepo je kaakiri ipinle Eko.
Ogagun agba Slyvanus Abbah to n dari iko omo ogun iwo oorun awon omo ogun oju omi lo siso loju ifilole naa ni Majidun nilu Ikorodu. O menuba Pataki ise akanse yii Labe ise akanse AWATSE to tumo si fon won ka ni ede Hausa. O ni:”Ise akanse AWATSE ti bere tele. Mo mo pe gbogbo awon to n gbe ni Eko ti rii pe odun keresimesi todun yii je okan lara awon to lo ni pele putu ju lo nitori awpapo aown omo ogun n sise takuntakun lati din ise awon onise ibi ti won wa latibo miran ku lopopona ati lori omi. Fun apeere, a ti mu aown ika ti won jale gbeyin leti omi nipinle Eko, a rii pe won kii se ara ipinle Eko rara sugbon won ni awon agbodegba lati ipinle Eko ti gbogbo won si jo wa latimole bayii. E maa woye pe ko si ajinigbe to ji enikeni geb lasiko odun keresi yii rara. Mo n gboriyin fawon omo ogun ti won n sise ki ohun gbogbo le wa niroworose”.
Abbah ni won yoo sise papo pelu awon omo ogun to n sise akanse lori jijeki ipinle Delta wa ni alaafia lati gbogun ti awon to n wonu odo lo ji epo robi wa ti won n ba opa epo je kaakiri agbegeb Naija-Delta.
Abbah nise akanse Jagunlabi yii yoo maa tesiwaju ni nitori sise ifilole yii ni lati se koriya fawon omo ogun ati ki aown onise ibi fi mo pe Majidun ti kuro nibudo jiji epo wa mo.
Awon miran ti won wa nibi ifilole ise akanse Jagunlabi ni Ogagun omo ogun ofurufu Ibrahim Yahaya, Ogagun Peter Dauke, Ogagun Beecroft, Ogagun Maurice Eno.
Ise akanse Jagunlabi bere  lati odo Majidun lo si ese odo waterside  lo si Ibeshe lo si Oworonshoki pelu inu aown oko oju omi akero gbogbo.
Ti ori ile bere lati Majidun lo si ibudoko ero Ikorodu lo si Ibeshe lo si Ilaje, Imota, pada si Ishawo.
Abbah ro awon omo ogun eka meteeta lati fowosopo ki won ji giri sise ile baba won ki okan awon eniyan le bale ni agbegbe wonyii fun idagbasoke Naijria lapapo.

No comments:

Post a Comment