Eniyan mejila doloogbe ninu ijamba ina ni New York - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Monday, 1 January 2018

Eniyan mejila doloogbe ninu ijamba ina ni New YorkO kere tan, eniyan mejila lo ti gbemi mi ninu ijamba ina to sele nile gbigbe awon eniyan ni Bronx Borough ni New York. Alakoso ilu New York, Bill de Blasio ni omo odun kan pere naa wa lara awon to ku sinu ijamba ina naa ti awon merin miran farapa yanayana.
Ko tii si oro lori ohun to sokunfa isese ina naa ni agbegbe Prospect nitosi Fafiti Fordham ati ogba eranko Bronx zoo. O le ni ogofa awon panapana ti won wa pese iranlowo nibi isele naa to bere ni nkan bii aago meje asiko won.
Ogbeni De Blasio ni won ti so ile iwe kan to wa nitosi ibe di ibudo ipago fawon eniyan toro kan lati farapamo si lataari otutu buruku to n ba won finra lekun naa lasiko yii.
O le ni ile adagbe ogun to wa ninu ile alaja marun un naa ti won ti ko ni o le logorun un odun seyin gege bi iwe iroyin New York Times se se akosile re.

No comments:

Post a Comment