Olopaa Sudan tu awon afehonu-han ka - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Wednesday, 10 January 2018

Olopaa Sudan tu awon afehonu-han ka

 Image result for sudan police

Awon olopaa lorile-ede Sudan yin ata taju-taju lati fi tu awon afehonu-han ka  lojo-Abameta, awon afehonu-han ti iye won to irinwo ni won n fehonu-han kaakiri ilu Sennar latari, bi buredi se gbowo lori.
Ko si iroyin to fi mule lasiko pe, awon eniyan padanu-emi won tabi enikankan fafa pa.
Owon gogo ori buredi ohun waye latari bi ijoba se yowo owo iranwo ninu eto isuna re ninu ose ti a wa yii.
Owo ori oja buredi lo soke ni ilopo meji gege bi awon onile buredi se so leyin ti owon gogo ti ba iyefun buredi naa.
Afehonu-han kan so pe, “ A n se iwode ifehonu-han lonii latari owon gogo owo ori buredi, eyi ti a ro ijoba lati wa woroko fi sada”.
A ko lee ra buredi kan ni pound kan, gege bi afehonu-han naa se so”.
Olori egbe alatako kan gboogi lorile-ede naa ti pe fun eto iwode alaafia tako owon gogo owo ori buredi naa, ni eyi ti o ko awon eniyan jo siwaju ile-ise buredi nilu Khartoum lojo-Eti, ninu eyi ti o ti fi erongba inini-lara ijoba mule.
Ijoba orile-ede Sudan ti bere olokan-o-jokan atunto eto oro-aje, ni ibamu pelu ilana ajo ayani-lowo lagbaye, pelu erongba ati mu igberu ba eto oro aje orile-ede naa.
Eto oro-aje naa ko fara ro latigba ti orile-ede South Sudan ti da duro ni odun 2011, eyi ti o ko ida meta oro epo-robi ti o je ona kan gboogi ti owo ile-okere ti n wole sapo ijoba.
Owo orile-ede Sudan ti wale lati osu kewaa nigba ti orile-ede America ti gbese kuro lori ofin ti won gbe le  kata-kara orile-ede naa lati bi ogun odun seyin.


No comments:

Post a Comment