Olori ijoba Egypt teleri yokuro ninu idije sipo Aare - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Wednesday, 10 January 2018

Olori ijoba Egypt teleri yokuro ninu idije sipo AareOlori ijoba teleri lorile-ede Egypt Ahmed Shafik ti so pe, oun ko nife si didije ninu eto idibo si ipo Aare ti yoo waye ninu odun ti a wa yii, o soro yii ninu atejade kan ti o ko sori ero ayelujara Twitter lojo-Aiku.
Shafik ni won ri gege bi eni ti o le figa gbaga pelu Aare Adbel Fattah al-Sisi ninu eto idibo ti yoo waye laipe yii, bi o tile je pe, Aare Sisi koi ti kede pe oun yoo dije ninu eto idibo naa.
Shafik pada sorile-ede Egypt lati United Emirates ninu osu kejila odun, leyin ti o ti fi erongba re han lati dije ninu eto idibo naa, ni eyi ti o fa awuyewuye kan nile-ise iroyin orile-ede naa pe, awon alase ti mu nigbekun sinu ile-itura kan nilu Cairo.
Omo odun merindinlogorin, ti o je ogagun omo-ogun oju ofurufu teleri , ti o tun ti figba kan ri je minisita fun eto irina oko ofurufu, ni o fidi remi ninu eto idibo si ipo aare ni odun 2012 ki o to rin irinajo lo si Unted Emirates, nibi ti fi se ibujokoo latigba naa.
Shafik salaye lojo-Aiku pe,pipada sorile-ede Egypt lo je ki oun yiiri ipinnu ohun wo.
O so ninu atejade ohun pe, “ Aisi si nile oun fun bi odun marun-un, lo sokunfa aije ki oun mo awon nnkan to n lo lorile-ede Egypt mo, nipa awon idagbasoke ati awon aseyori, bo tile je pe, nnkan naa ko fara ro to bee”.
 “Mo ti ri bayii pe, mi ki se eni to le dari orile-ede naa ninu eto idibo ti yoo waye laipe yii, eyi ti o je ki yii ipinnu mi pada wi pe, emi ko ni le kopa ninu idije si ipo aare ti yoo waye ni odun 2018 ti a wa yii”.

No comments:

Post a Comment