Niajiria ja-wale ninu ipo ate ajo FIFA - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Sunday, 18 February 2018

Niajiria ja-wale ninu ipo ate ajo FIFANairijia jawale ninu ipo ate tuntun ajo FIFA, eyi ti igbimo to n ri si boolu afesegba lagbaye gbe jade lojo-Bo(Thursday).
Gege bi atejade ajo FIFA ti o jade ninu ero ayelujara won lojo-Bo(Thursday) se so, Iko agbaboolu Super Eagles ti o wa ni ipo mokanleladota lagbaye pelu ami egbeta-lemokanleladota ninu osu-kinni odun yii.
Ni bayi, iko ohun ti wa ni ipo mejileladota pelu ami egbeta-lemefa
Bakan naa, Naijiria sepo keji ninu idije CHAN  ti o waye lorile-ede Morocco.
Ewe, leyin ti iko ohun jawale ninu atejade ipo ate FIFA losu ti o koja latari didin ami iko naa ti won fi pegede fun idije boolu agbaye, opo ninu awon ololufe iko Super-Eagles lo fokan si pe, ipo ate miran yoo wa soke, sugbon ti ko ri be.
Ni bayi, Super Eagles dipo keje mu nile-Afrika, ti orile-ede Tunisia, Senegal, DR Congo, Morocco, Egypt ati Cameroon si tele ra-won.
Orile-ede Ghana, Burkina Faso ati Algeria naa tele ra-won pelu ipo kejo, kesan-an ati ikewa lori ipo ate tuntun ohun.
Ni ipari, Germany wa ni ipo kinni, Brazil ipo keji ti Portugal si sepo keta lagbaye.
Ipo ate tuntun miran yoo tun jade lojo karundinlogun osu keta odun ti a wayi.

No comments:

Post a Comment