Iniesta- Mi o ni kopa fun Spain mo leyin idije boolu agbaye - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Saturday, 24 March 2018

Iniesta- Mi o ni kopa fun Spain mo leyin idije boolu agbayeSaaju ifigagbaga olorejore ti iko agbaboolu Spain yoo gba pelu Germany lojo Eti(Friday), atamatase iko ohun, Adrie Iniesta ti kede pe oun ko ni kopa fun iko naa mo leyin idije boolu agbaye todun yii.
Iniesta, ti gba ifesewonse mẹ́tàlélọ́gọ́fà fun Spain bayii, sugbon ti koi ti ba  tawon asaaju re ti won ti feyinti bi: Andoni Zubizarreta, Xavi, Sergio Ramos ati Iker Casillas.
Ni bayii, ti Iniesta baa lanfani lati kopa ninu olokan-o-jokan ifesewonse olorejore fun Spain, eyi yoo mu saaju akegbe re teleri, Xavi leni ti o je eniketa ti o kopa julo fun iko agbaboolu Spain ki o to feyinti ni omo odun merinlelogbon.
“Ni bayii, o farahan gbangban-gbangban pe, idije agbaye to n bo yii ni yoo je ikeyin ti ma kopa ninu re fun Spain ,” 
Iniesta je okan lara agbaboolu iko Spain ti o saaseyori julo ninu itan iko ohun, leyin ti o ran won lowo lati gba ife-eye European Championship ni saa 2008 ati 2012, beesini O tun kopa fun iko naa ninu idije agbaye lodun 2010, ti o si tun gba ife-eye idije naa.

No comments:

Post a Comment