Opo awon adajo Naijiria gan-an ni olori ole – Aafaa Muideen Bello - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Saturday, 24 March 2018

Opo awon adajo Naijiria gan-an ni olori ole – Aafaa Muideen Bello

B

Shehu Muhideen Bello so o di mimo pe opo awon adajo ilu yii ni olori ole ninu fidio iwaasu won kan.
Gege bi won ti so o, won ni ti a ba wo ibi ti wahala Naijiria ti bere, debi ti o de lonii, odo awon adajo wonwonyii ni.
Won ni, pe won a koko ri owo ti won jiko nilu yii, sebi odo awon adajo wonyi ni, sebi e si ni won ki n se ole? Ni ohun ti won wi.
Baba tun so o di mimo wi pe se owo ti won n gba losoosu naa ni won fi n kole kaakaakiri adugbo.
Aafaa Bello ni, “E ko ri ibi a ba ara wa de lonii? Olorun ko ni je ki a kuu be. Iya yii po pupo ju, o koja afenuso.’
Won wa se epe nla le awon ti n da ilu yii ru pe “eyin ti e seeti iya yii fun wa, aramodomo yin inu iya ni won yoo ku si”.
Won ni Olorun so ninu Alikurani pe, “Oun so Kurani yii kale lori ododo, ki o le maa fi se idajo fun awon eniyan lori gbogbo ohun ti mo fi han o (iyen Anabi Muhammad (s.a.w))”.
Won wa gba orile ede yii nimoran pe ki won lo oro Olorun yii ninu eto aye won, ki won pe ole lole, ki won pe jaguda ni jaguda. Ko lee pe mo nisin-in ti awon omo won yoo bere si ni wu oku oloku nigba ti o je wi pe egbe saare,egbe oku ni won tun n sin owo si bayii. Se a wa ni ijoba ree?, aa ni ijoba rara, ni ohun ti won tun wi.
Won tun so o di mimo pe, enikan soso ni o mo ninu gbogbo awon ti n se ijoba, eni naa si ni ilu Naijiria fi se olori, pe gbogbo nnkan ni won si n ko bo o, bi won se n be awon wolii lati sa si i bee ni oso ile, aje ile, awon babalawo ati awon alufa ni won n ta owo si i ti won ko je ki o gbadun aye re. A wa n so pe ko gbadun lonii, o n saare lola nigba ti o je wi pe oun nikan ni o mo laarin gbogbo won.
Won tun tesiwaju pe, owo ti mekunnu ilu ko ri na ni won wa ko pamo si inu iyara, won tun wa si ero oloye si i lori ki o maa tutu, “oru si n mu eniyan, owo si n tutu”. E tun wa ko awon eniyan sita ki won maa so eni ti o ba fe de ibe, won ni; tani yoo wa de ibe, sugbon olorun ti o seda won ti o mo asiri won naa ni yoo tuna asiri won, bee o si n tu asiri won leekan kan bayii.

No comments:

Post a Comment