Ajo HAJJ fojokun iforukosile irinajo lo si ile mimo - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Monday, 9 April 2018

Ajo HAJJ fojokun iforukosile irinajo lo si ile mimo

AJO HAJJ fojokun iforukosile irinajo lo si ile mimo

Igbimo to n mojuto irinajo awon musulumi lo sile mimo, ni ipinle Kaduna ti fi kun ojo to ye ki gbedeke ba iforukosile  awon eniyan naa, lati ojo kokanlelogbon osu keta  di ogbon ojo, osu kerin.
Alukoro fun igbimo yii , mallam Yunusa Abdullahi lo so eleyii di mimo ninu atejade kan lojobo ni ipinle Kaduna.
O wa so fun gbogbo awon arinrinajo to ti foruko sile ni ipinle naa lati san milionu kan ati aabo naira( N1.5m) ko to di ojo karundinlogbon osu kerin odun yii, ki ajo to n mojuto irinajo lo si Hajj lorile ede Naijiria  to kede iye awon arinrinajo to n lo lodun yii.
Atejade yii tun so pe ajo to n mojuto irinajo lo si Hajj lorile ede Naijiria  lo fi kun gbedeke ojo  to ye ki iforukosile naa wa si ipari
Abdullahi so pe iforukosile awon arinrinajo naa yoo tun tesiwaju di ojo karundinlogbon ,osu kerin  lati le je ki igbimo naa le e se ojuse won ko to di ojo ti gbedeke  iforukosile naa yoo wa si ipari ati lati le  gba gbogbo owo ti won ti san wole si ajo NAHCON ko to di ogbon ojo , osu kerin.
O tun tesiwaju pe , igbimo naa ti gba awon ibugbe to dun un gbe fun awon arinrinajo naa.
Agbenuso igbimo naa tun so pe ,awon eniyan ti iye won ko din ni ẹgboókànlá ni won ti foruko sile lara awon eniyan  to le ni , ẹgbàáta ti igbimo naa ti pese ijokoo fun  .

No comments:

Post a Comment