Ayeye odun Ajinde:owo-ori oja ounje fo soke ni Eko - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Sunday, 1 April 2018

Ayeye odun Ajinde:owo-ori oja ounje fo soke ni EkoSaaju ayeye odun ajinde, owon-gogo bi iko ogorun ninu ida ogorun 100%, ti ba owo-ori oja awon ounje bi: tomati, ata rodo, alubosa ni awon oja kaakiri ipinle Eko
Iwadii so lojo-Bo ni oja Mile 12, Ile-epo ati Oyingbo safihan pe, apere tomati, eyi won n ta ni egberun merin abo N4,500 tele ninu osu to koja, ti di egberun mesan abo  N9,500 bayii.
Apere ata-rodo ti di egberun mejo N8,000 lati egberun merin abo N4,500 tele, nigba ti apere tatase ti di egberun mejo N8,000 lati egberun merin N4,000 ti o wa tele.
Apo alubosa ti won ta ni egberun metala N13,000  tele, ti di egberun merinla N14, 000 bayii, nigba ti apo ewa ti egberun lona ogbon atabo N30,500 bakan naa ni apo iresi di egberun mejidinlogun atabo N18,500 lati egberun metala N13,000 tele ri
Kilo Turkey kan ti di egberun kan o-le N1,350.00, nigba ti won n ta adiye inu yinyin ni egbefa N1,200 naira, amo dirika garri si duro lori odunrun N350 naira.
Awon oloja so pe, awon oja n gbowo lori lasiko odun bayii, latari aleku lowo ori irina-oko ati awon ipenija eto-abo ti won n koju ni apa ariwa ila-orun orile-ede Naijiria.
Alhaji Hamzat Abudulkarim, ti onisowo oja ata ni oja ti o wa nile-Epo so pe, adinku ti ba iye iwon oja ti won n gbe wa, toripe o je oja ti o ni asiko.
O salaye pe, “oja tomati maa n lo nigba miiran, toripe o ni asiko, ni eyi ti alekun ti ba owo ori re  lati ipinle Kano, Sokoto, Zaria ni awon ibi ti a ti n ra won”.
Ogbeni Femi Odusanya, ti o je agbenuso fun egbe awon oloja ewe-be loja Mile 12 so pe, o pon dandan ki awon ipele ijoba meteeta mu alekun baa won agbe elewe-be, lati mu igberu ba ipese ounje, ni eyi ti o n ro ijoba apapo lati kowo lori gbigbe odo kaakiri orile-ede Naijiria, lati le mu igberu ba eto ogbin lasiko ogbele.

No comments:

Post a Comment